Liberia School Inferno: Ọmọ ilé ìwé tí kò dín ní métàlélógún ló gbèkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra ní Liberia.

Liberia
Àkọlé àwòrán Liberia

Ko din ni metalelogun awọn ọmọ ile iwe kan ni orilẹ ede Liberia ti wọn ṣe bẹẹ gbẹmi mi latari ina ti o suyọ.

Iṣẹlẹ yii ni o ṣẹ ni kutukutu owurọ oni nigba ti awọn ọmọ naa ṣi n sun ni ileegbe ti o wa ni inu ọgba awọn akẹkọọ naa.

Ile iwe yii ni o ni ibugbe awọn akẹkọọ ti o si wa ni ẹba ile ijọsin Mọṣalaṣi kan ni olu ilu orilẹ ede naa, Monrovia.

Nigba ti awọn Ọlọpaa n ṣalaye ọrọ naa fun ikọ ile iṣẹ BBC, wọn ni lọwọlọwọ yii, ajoku ara awọn ọmọ naa ni wọn ṣi n ko kuro.

Nigba ti Alukoro ajọ Ọlọpaa ilẹ naa, Moses Carter n ba Akọroyin sọrọ, o ni ina mọnamọna ni o ṣokun fa iṣẹlẹ naa ti iwadii si n lọ.

Awọn Oṣiṣẹ ibẹ ṣalaye pe, awón ọmọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si ko ju ọmọ ọdun Mẹwa ati ogun ọdun lọ.

Bakan naa ni iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe awọn ajọ alawọ pupa ti n ko oku awọn ọmọ naa kuro ti wọn yoo si si n wọn ni Ọsan oni.