Lizzy Anjorin vs Toyin Abraham: Lizzy Anjorin tún rọ òjò ọ̀rọ̀ tuntun lórí Toyin

Lizzy Anjorin Image copyright Lizzy Anjorin/Facebook
Àkọlé àwòrán Lizzy Anjorin

Bi o tilẹ jẹ pe awọn agba ọjẹ ninu ere sinima Yoruba n wa ọna lati pari aawọ to wa laarin Lizzy Anjorin ati Toyin Abraham, o dabi ẹni pe opin ko tii de ba aawọ naa.

Eredi ni bi Lizzy ṣe sọ oko ọrọ miiran si Toyin Abraham ninu fidio kan to fi soju opo Instagram rẹ.

Ninu fidio yii ni Lizzy ti sọ pe, ẹbẹ ti oun bẹ ṣaaju kii ṣe fun Toyin, ṣugbọn fun awọn ẹbi ati awọn ololufe oun ni.

Fidio tuntun yii ni Lizzy gbe jade lẹyin ti awọn oniroyin kan n gbe iroyin pe, o ti rawọ ẹbẹ si Toyin, sugbọn o ni ọrọ ko ri bẹẹ rara.

Ninu fidio mii ti Lizzy gbe jade yii lo ti ni "Ẹbẹ ti mo bẹ kii ṣe fun Toyin, sugbọn o wa fun awọn ẹbi ati awọn ololufẹ mi ni. O ni, opurọ gbaa ni Toyin, ile alagbo ọmọ lo bimọ si."

Wọ k'ilu mọ oṣere sinima naa ni, bi Toyin ko ba dẹkun ibajẹ lori ọrọ oun, ija ṣẹṣẹ bẹrẹ laarin wọn ni.

O ni ohun ti Toyin ṣe fun oun jẹ ohun to buru jọjọ, fun idi eyi oun ko le rawọ ẹbe si Toyin, bẹẹ ni oun ko ni simi agabja.

O wa pari ọrọ rẹ pe ọrọ pe, kesekese ni Toyin si ri, kasakasa si n bọ lọna.