'Mo fọ kọ́mú, pátá, ògiri ilé lórí N200,000 láìlèfọhùn lórílẹ̀èdè Oman'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Oman Slave: Mo fọ kọ́mú, pátá, ògiri ilé 'torí N200,000 irọ́

Ohun taa jẹ, taa mu, taa fi r'ile aye gbe lo mu arabinrin yii ti a ko le fi oju rẹ han kuro ni Naijiria lọ gba iṣẹ ni orilẹede Oman.

Arabinrin yii sọ fun BBC pe jẹjẹ loun wa nilu wọn ti wọn sọ fun un pe iṣẹ wa ni orilẹede kan ti wọn yoo ti maa san owo to to igba miliọnu naira fun un.

"Bi kii ba ti ṣe iṣẹ aṣẹwo, o dara". Ni arabinrin yii fesi fun awọn aburo rẹ to ba a wa iṣẹ.

O de 'bẹ tan lorin ba yipada.