South Africa: Kò pọn dandan fún mi láti tọrọ àforíjì lówọ Nàìjíríà - Herman

Mayor Mashaba
Àkọlé àwòrán Mashaba of Johannesburg

Alakoso ilu Johannesburg ni orilẹ ede South Africa, Herman Mashaba ti sọ wi pe oun ko ni idi kankan lati tọrọ aforiji lọwọ orilẹede Naijiria.

O ni ko si idi pataki kan pato fun oun lati rawọ ébẹ si awọn ọmọ Naijiria latari ikọlu ti o waye ni ilẹ naa.

Ṣe ni ẹnu aipẹ yii ni awón ọmọ Orilẹ ede South Africa ṣe ikọlu si awón ọmọ Naijiria to n gbe ni ilẹ naa ti wọn si ba ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye jẹ ti ọpọ si di alairile gbe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSouth Africa: Àwọn ọmọ Nàìjíríà tó kù ní ìjọba SA ń kó ọ̀pọ̀ tó fẹ́ wále sí ọgbà ẹ̀wọ̀n

Ninu ifọrọwerọ pelu awọn akọroyin lo ti ṣalaye pe ko si idi to yẹ ki oun fi tọrọ aforiji lọwọ ijọba tabi ọmọ orilẹ ede Naijiria.

Mashaba wi pe ko din ni millọnu mẹwa awọn ọmọ ilẹ naa ni ko niṣẹ latari ayederu eru ti wọn ko wọle lọna aitọ ti o si n ṣe akoba fun idagbasoke ile iṣe wọn.

Ninu ọrọ rẹ naa lo ti tẹsiwaju pe, ero orilẹ ede naa ni lati rii wi pe iwe ofin igbelu yoo fẹsẹmulẹ laipẹ ki opin le deba iwọlewọde lọna aitọ.

Ṣe ṣaaju ni olori orilẹ ede naa, Aarẹ Ramaphosa ti bẹ ijọba ati gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria fun ikọlu to waye naa.