Kwara Flooding: Ìjọba ipinlẹ Kwarai fi ẹhonú hàn lórí iṣẹ́ àjànbàkú Odò Ásà

Gomina Ipinle Kwara Image copyright Kwara Govt
Àkọlé àwòrán Kwara Flooding: Ìjọba ipinlẹ Kwarai fi ẹhonú hàn lórí iṣẹ́ àjànbàkú Odò Ásà

Gomina Ipinlẹ Kwara AbdulRahman AbdulRazaq ti parọwa si ijọba apapọ lati ṣe awári agbaṣẹsẹ fífẹ ojú odò Asa pada.

Nigba ti o n ṣe abẹwo si iṣẹ ajanbaku ti awọn agbaṣẹṣe naa ṣe si fifẹ oju agbara odo naa ti o si ti ṣe jamba lọpọlọpọ.

Sẹ saaju ni Gomina naa ti ni oun ti kọ iwe si ijọba apapọ lori iwa tani yoo mumi ti awọn agbaṣẹṣe naa wu lori iṣẹ naa.

Ijọba ipinlẹ naa wa kẹdun lori iṣẹlẹ ti o mu ẹmi arabinrin Adeyemi Lateefah lọ ni ọjọru ọsẹ yii latari iṣẹ ajanbaku naa.

Lateefah ni o ṣe agbako iku ojiji yii nigba ti o lọ si ibudokọ Maraba ninu ojo ti ẹsẹ rẹ si yọ ti omi naa si gbe lọ.

Agbara omiyale ni ilu llọrin ti wa pọ to bẹẹ gẹ ti gbogbo oju ọna ko ṣe egba mọ ni pasẹ omi ti ko rọna lọ daada yii.

Arọwa ti wa lọ sọdọ awọn ti o n gbe ni agbegbe ibi ti omi yale yii ti ṣọṣẹ lati kuro ni agbegbe naa titi ti ijọba yoo fi wa wọrọkọ ṣada.

Awọn alaṣẹ ipinlẹ naa ti wa ba ẹbi oloogbe naa kẹdun pupọ lori iku ojiji to pa arabinrin yii,pe opin yoo ba omiyale laipe ni ipinlẹ naa.