Europa League - ìnàkunà ni Arsenal na ojúgbà rẹ ti Frankurt.

Arsenal FC Image copyright Arsenal portal
Àkọlé àwòrán Arsenal Football club

Ẹgbẹ agbaboolu Arsenal ti fi agba han ojugba wọn Eintracht Frankurt pẹlu amin ayo mẹta si odo.

Willock gba bọọlu akọkọ wọ inu àwòn Frankurt ni nkan bii iṣẹju metalelọgọta ti ere naa bẹrẹ.

Nigba ti amin ayo keji wọle nigba ti o ku iseju marun ki ere pari ti Bukayo Saka ṣokunfa wiwọ le bọọlu naa.

Bo ti lẹ jẹ pe, ẹgbẹ agbaboolu Frankurt ni ọpọlọpọ anfaani lati gba bọọlu wọ inu awọn ile Arsenal sugbọn ti nkan ko sẹnu u re fun wọn.

Lọgan ni ẹgbẹ agbaboolu Arsenal ti fi ikan si fun ojugbaa rẹ nigba ti o ku iṣẹju meji ki ere pari.

Ewuro ti egbe agbaboolu Arsenal gbo si oju Frankurt yii mu irẹwẹsi ba gbogbo awọn alatilẹyin wọn lọpolọpọ.

Image copyright CLUB PORTAL
Àkọlé àwòrán Frankurt FC