Lizzy Anjorin vs Toyin Abraham: Ẹ wá ọ̀nà láti parí ááwọ̀ ààrin yín - Yomi Fabiyi

Lizzy, Toyin, Kemi
Àkọlé àwòrán Toyin Vs Lizzy: Ẹ wá ọ̀nà láti parí ááwọ̀ ààrin yín- Yomi Fabiyi

Ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin láti kí ìdà wọn pada sápó, nítori pé, ọ̀nà tí ǹkan ń gbà lọ yìí kò bóju mú rárá.

Ilúmọ̀ọ́ká oníroyin Kemi Olunloyo ké sí Toyin pé ko lọ mu omi sùúrù o, nítori pé gẹ́gẹ́ bi abiyamọ tó jẹ, oun, lo nílo sùúrù jùlọ, Bakan náà lo ké si Lizzy pé, lábẹ́ àkoso bo ti wù kó rí pe, kìí ṣe ǹkan to tọ̀nà láti maa ṣepe fún ọmọ làkeji, pàápàá jùlọ ọmọ tuntun to ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ wá sáyé.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWùnmí Toríọlá: Toyin Abraham kìí se ọ̀gá mi nínú tíátà

O ní kò si ìgbà kankan ti Toyin parọ pé òkè okun ni òun bímọ sí bíkoṣe ìlú Eko.

Kemi Olunloyo rọ ìhà méèjèjì láti simi àgbaja kí wọn sì tẹ̀síwáju ninu ìrìnajo ayé wọ́n.

Gbájugbàja òṣere Yomi Fabiyi náà ti bọ sita láti pẹtu sí ààwọ̀ àwọn òṣèré tíátà méjèèjì láti fi òpin si ááwọ̀ to wà láàrin wọ́n, pàápàá jùlọ wọn le sàlàyé oun to ń jẹ wọ́n lọkan fún àwọn asaaju ẹgbẹ òṣèré tíátà.

Lóju òpó Instagram rẹ̀ lo ti pàrọwà náà pé, òun kò nik ẹtọ́ botiwù kí o mọ láti tàbùkù ẹnikan tàbi dá ẹnikéni lẹbi nítori òun ko mọ ibi ti bàta ti n ta wọ́n lẹ́sẹ̀, sùgbọ́n ó ṣe pàtàkì láti fòpin si ààwọ náà ki wọn le tẹsíwáju pẹlu ayé wọ́n.

Ọgbẹ́ni Fabiyi ni kò si ohun to le ti ko ni rọ nítori náà o ti pọ́ndandan láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lóri ọ̀rọ̀ náà.