Lizzy Anjorin vs Toyin Abraham: Àwọn òṣere tíátà ayé òde òni ko ni ọ̀gá ti wọ́n n tẹ̀lé- Idowu Philips

Iya Rainbo Image copyright Mama Rainbo
Àkọlé àwòrán Àwọn òṣere tíátà ayé òde òni ko ni sgá ti wọ́n n tèlé- Idowu Philips

"Ọmọde ló ń se àwọn òṣèré ayé òde òní"

Gbájúgbajà àgbà òṣèré tíátà, Idowu Philips ti gbogbo ènìyàn mọ si ìyá Rainbow sọ bi wọn ṣe bọwọ gidi gan fun awọn aṣaju ninu ere tiata laye igba ti awọn bẹrẹ.

Lásìkò tó ń ba BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, Iya Rainbow ní lásìkò ti òun wà léwe ninu iṣẹ́ tíátà, kò si ẹni ti wọ́n bíire láti maa jà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPottery: Àwọn onímọ̀ nípa amọ̀ wúlò púpọ̀ ju ike àbí irin lọ

"Àwa kìí jà lásìkò ti wa, ta lo bi ẹ ti wa maa jà? níbi ti àwọn ọ̀gá wà"

" Ẹ má dáwọ́n lòun, ọmọdé lo n ṣe àwọn ọmọ yẹn, wọ́n o lọ́gàá, wọ́n o ru pọtimọtò, wọ́n o si ni ìbẹ̀rù fú àgbà."

Ó fi kún un pé àwọn òṣere ayé ode oni kò ni ẹ̀mí ìbẹru, àti pé ǹkan to tún wá buru julọ ní ayélujara àti gbogbo àwọn ìrinṣe ibára ẹnisọrọ ti wọ́n ti ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ si àrà wọ́n.

Gbajúmọ òṣèré náà tún sàlàyé pé gbogbo awuyewuye to n bẹ́ sílẹ̀ lágbo tíata yóò ni ìyanju láìpẹ́, nítori pé àwọn àgbà ẹgbẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ si ni gbé ìgbésasẹ̀ láti fopin si gbogbo ìwà pálapàla to ń wáyé.

Bákan náà lo ṣàlàyé pé kò si agbé má jà ṣùgbọ́n tí kìí ba ṣe pé ìwà ọmọde, o ṣe pàtàkì láti wá ọ̀na ti wọ́n o gba láti pari rẹ̀ kìí ṣe pe ki a maa gbé ara ẹni lo sóri ayelujára.