Port Harcourt: Afurasí wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá

Kọmíṣánà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Rivers, Mustapha Dandaura Image copyright Mustapha Dandaura/Facebook
Àkọlé àwòrán Ìpaǹìyàn ni Port Harcourt

Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ Gracious David West, ẹni ti wọn fura si pe o pa ọpọlọpọ obinrin ni ipinlẹ Rivers.

Ninu fidio kan ti ajọ ọlọpa fi lede loju opo Twitter rẹ, afura naa ni a ri to n jẹwọ bi o ṣe pa obinrin kan ni ile itura kan ni Port Harcourt.

David West ṣalaye ninu fọnran naa bi o ti gbe obirinrin kan kuro ni ile ijo to si lọ paa nile itura kan.

Ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn ọhun to ti olpaa funrasi pe o jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ okunkun Degba ni ọwọ ofin tẹ ni opopona Port Harcourt si Uyo.

Kọmiṣona ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers, Mustapha Dandaura ni, afurasi ọhun ti fun awon agbofinro ni awọn iroyin kan, bẹẹni iwaadi awọn yoo ṣe koko lori idi ti afurasi naa ṣe n fi n gbẹmi awọn eniyan, ati lati mọ awọn alabaṣeṣẹpọ rẹ.