Lagos-Ibadan Accident: Léyìn òkú marun un, ènìyàn méwàá wà nílé iwòsàn.

Lagos-Ibadan Accident Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kò dín ní èniyàn marun un tó gbémi mí tí ọpọ sì farapa yánnayaǹna nínú ijamba ọkọ ni popona ìlú Èkó sí Ìbàdàn.

Ko din ni eniyan marun un ti wọn jona raurau ti mẹwa si fara pa yannayanna ninu ijamba ọkọ to waye ni popona lbadan si llu Eko.

Ijamba yii lo waye nigba ti ijanu ọkọ ayọkẹlẹ kan ni agbegbe Onigari loju ọna naa sọ iṣẹ silẹ latari ere asapajude.

Nigba ti ile iṣẹ BBC Yoruba n ba Ọga Agba Ẹṣọ Abo oju popo,Clement Ọladele sọrọ lori isẹlẹ naa, o ni ibanujẹ gbaa ni iṣẹlẹ naa jẹ.

O tesiwaju pe, nkan bii aago mẹsan aarọ ọjọ Eti ni iṣẹlẹ yii waye ti ọkọ ayọkẹlẹ yii fori sọ ogiri aarin ọna ti o si fori sọlẹ .

Ọladele ṣalaye pe ni igba ti ọkọ naa n fori sọlẹ, lo ba lọ kọlu ọkọ elero pupọ kan ti o n bọ lati ilu Sokoto.

Ni bayii, eniyan mẹwa ni wọn ti ko lọ si ile Iwosan fun itọju ni ile lwosasn Olabisi Onabanjọ Yunifasiti, Ṣagamu.

Oku awọn marun un naa ni wọn ti ko lọ si ibi igbokusi ile iwosan naa.

Ọga agba naa ti wa rọ awọn awakọ lati din ere ku loju popo naa yii ati pe, iṣẹ n lọ lọwọ loju ọna naa.