Ṣé ẹ fẹ́ mọ ìgbà tí ẹ̀fọn meji bá ń kọ orin ifẹ́ léti yín?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Malaria Mosquitoes: Ẹyẹ nìkan kọ́ ló ń kọrin, ẹ̀fọn náà ń kọ

Titage ìfẹ́ laarin awọn ẹranko ti Ọlọrun da nigba miran ko le lati mọ nitori pe ọpọ eniyan n ba wọn gbe tabi ṣetọju wọn.

Nitorinaa fun apẹrẹ, àwọn ẹyẹ nìkan kọ́ ló lóhùn orin, ẹ̀fọn náà ń kọ koda wọn ni eyi ti wọn n kọ yatọ fun ibalopọ laarin akọ ati abo.

Nínú fídíò yìí lẹ ti leè gbọ́ kedere, orin ìfẹ́ tí wọ́n máa ń kọ́ ṣáájú ìbálòpọ̀.

Iyẹ awọn ẹfọn lo maa n da orin silẹ.

Abo ẹfọn maa n kọrin pẹlu ohun isalẹ tori iyẹ rẹ kere, iru ohun yẹn ni eyi ti awọn eeyan maa n pe ni ohun inu yara.

Eyi si lo ma n jẹ ki akọ ẹfọn da ohun abo mọ laarin ọgọọrọ kokoro ko da ko ma jẹ laarin ẹfọn.

Awọn oniwadi ti tun tu idi aṣiri awọn wo titi wọn fi ni awọn lee kọ orin ifẹ laarin awọn ẹfọn lati lee da wahala silẹ lagbo ẹfọn ki adinku lee ba ijamba ti wọn n fa lara eniyan.