Sowore ń gbìmọ̀dìtẹ̀ láti gba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Buhari - Ìjọba àpapọ̀

Soyinka Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Tayọtayọ ni mo fi n ki Soworẹ kaabọ sagbo awa ti wọn ti fẹsun kan

Ọjọgbọn Wole Soyinka bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu ijọba Naijiria lori ẹsun ti wọn fi kan Soworẹ.

Gbajugbaja onkọwe Kongi ni ẹsun ti wọn fi kan Sowore pe o fẹ ditẹ gbajọba yii ku diẹ kaato.

O fi atẹjade naa sita pe ko dara bi ijọba ṣi ṣe fi Sowore Omoyele si ahamọ DSS ati pe ẹsun meje ti ijọba fi kan Soworẹ yii ko tọna.

Wole Soyinka ni oun ko kọkọ gba ẹsun ti oun gbọ lori Soworẹ gbọ nibẹrẹ ṣugbọn nigba ti ọrọ naa di ootọ ni o di kọọ.

Soyinka tun wa ki Ṣowore pe o kaabọ si agbo awọn ti wọn ti fẹsun kan ri.

O ni ki ijọba Buhari rọra ṣe pẹlu ootọ inu nitori gbogbo ohun ti a ba ṣe loni yoo di ọrọ itan lọla.

Wo ìdí ti ìjọba ṣe ka ẹ̀sùn méje tán yányán mọ́ Sowore lẹ́sẹ̀.

Ọrọ Revolution Now ti fẹ ba ibo mii yọ fun ọmọyẹle Soworẹ bayii gẹgẹ bi ijọba apapọ ṣe di ẹsun meje ru le e lori.

Bi ọjọ ṣe ń ka ọjọ latimọle fun oludasilẹ ẹgbẹ ajafẹtọ Revolution Now, Omoyele Sowore, ijọba apapọ Naijiria ti fi ẹsun meje kan an.

Ẹsun pe Soworẹ ń déte láti dìtẹ̀ gba ìjọba Nàíjíríà, ẹsun lilo owo baṣubaṣu atawọn ẹsun mii ni wọn fi kan an.

Image copyright BBC, @YeleSowore

Lorukọ adajọ agba orilẹede yii ati minisita fun eto idajọ, Abubalar Malami to jẹ amofin agba, ni agbẹjọro o wa ni ẹka ipẹjọ ile iṣẹ naa, Aminu Aliyu buwọlu iwe ẹsun ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRevolutionNow: Ẹ̀rù ò bàwá, a ṣetan láti wà ní àtì mọ́lé- olùfẹ̀hónúhàn

Gẹlẹ to ku ọjọ kan pere ki iye ọjọ ti ijọba ni ko fi wa latimọle o pe ni wọn na iwe ẹsun meje si i eyi to si fun ile isẹ ọtẹlẹ muyẹ laṣẹ lati sọ iye ọjọ atimọle rẹ di marunlelogoji.

Tẹlẹ, ọjọ ikọkanlelogun, oṣu kẹsan an lo yẹ ki atimọle rẹwa sopin.

Ninu iwe naa, olupẹjọ fi ẹsun kan Sowore ati ajumọja rẹ, Olawale Bakare pe wọn gbimọ pọ lati gba ijọba eyi to lodi si abala ofin 516 ninu ofin Naijiria nipa didari ifẹhonuhan lọjọ karun oṣu kẹsan pẹlu erongba lati yọ aarẹ orilẹede Naijiria loye.

Ẹsun ti wọn fi kan Sowore:

Bakan naa, wọn tun fi ẹsun kan pe wọn fẹ ko ero jọ ninu oṣu kẹjọ kaakiri ipinlẹ Eko, Abuja atawọn ibomiran lorilẹ-ede Naijiria lati ṣe iwọde ifẹhonu han #RevolutionNow lati le yọ aarẹ nipo.

Ẹwẹ, wọn tun fi ẹsun jijale lori ẹrọ ayelujara kan an eyi ti wọn ni o lodi si abala ofin 24 (1) (b) ninu ofin Naijiria.

Ẹsun lilo owo baṣubaṣu naa kun ohun ti wọn fi kan Sowore pe o lodi si abala 15 (1) ninu ofin Naijiria nipa pe wọn ni o fi owo ranṣẹ lọpọlọpọ igba nipasẹ ikani ti wọn n pe ni "swift transfer" lori ẹrọ ayelujara.

Ọjọ keji, oṣu kẹjọ ni ile ọwọ sinkun ajọ DSS tẹ Sowore nile rẹ l'Eko ṣaaju ki eto iwọde ifẹhonuhan to n pete to waye ti wọn si ti gbe e si atimọle.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood: Kò sí ẹni ti òbí mi kò lè sọ̀rọ̀ sí -Sisi Quadri