Lizzy Anjorin vs Toyin Abraham: Madam Saje, Antar Laniyan, àtàwọn míì wí tẹnu wọn

Osere Fausat Balogun Image copyright @madamsaje

Ni ti Toyin Abraham lori ija to wa nilẹ yii, ọna ka maa kọ iwe ranṣẹ si alatako lo n yan lati maa dahun bẹẹ si ni ni ti Lizzy, ṣiṣe fọnran jade sori ẹrọ ayelujara lati fesi loun yan.

Ayafi fidio kan ti Toyin fi sita lati ṣafihan pe lootọ loun bimọ sile iwosan to ṣe pe awọn dokita oyinbo lo n gbẹbi nibẹ, kii ṣe ile alagbo ọmọ gẹgẹ bi Lizzy ṣe n pariwo rẹ.

Lori eyi Lizzy ṣi tẹsiwaju lati maa tẹnu mọ ọ pe o da oun loju pe ile alagbo ọmọ lo bimọ si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWùnmí Toríọlá: Toyin Abraham kìí se ọ̀gá mi nínú tíátà

Bayi ni awọn mejeji yii si ṣe n ṣe pasiparọ rẹ lati igba ti ọrọ ija ti wọ aarin wọn. bo ba ya ọkan a simi ẹnu lati tun pada fesi, bo ba wu ọkan, a fesi ni tẹle n tẹle.

Ẹwẹ, yatọ si bo ṣe n lọ laarin awọn ololufẹ wọn lọtọọtọ ti Àwọn olólùfẹ̀ Toyin Abraham ati Liz Anjorin ti gbé ọ̀rọ̀ wọn rù sórí, ẹ wo òjò òkò ọ̀rọ̀ , awọn gbajumọ oṣere ẹgbẹ wọn ti n rọ awọn mejeji ṣugbọn ti wọn kọ lati gbọ pe "Ẹ lọ́ jáwé gbé jẹ́ẹ́ sọ́wọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́..." gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere Yoruba, Bolaji Amusan ti ẹ mọ si Mr Latin ṣe kilọ fun wọn. Bẹẹ naa ni Jaiye Kuti fesi lori fọnran ti wọn fi sita lati dupẹ fun igbesẹ wọn bi oun naa ṣe ti gbiyanju ranpẹ tirẹ.

Pẹlu agba oṣere mii bii Yinka Quadri, Antar Laniyan, wọn ni aarẹ ẹgbẹ awọn ti fi agba ba wọn sọrọ. Ko da iroyin sọ pe o ti ba ọkọ toun naa jẹ oṣere Toyin Abraham sọ ọrọ pupọ, bẹẹ si ni Kolawole Ojeyemi Ọkọ Toyin Abraham pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ lórí aáwọ̀ láàrin ìyàwó rẹ̀ àti Lizzy Anjorin nigba to fi ọrọ bi afiwe sita loju opo instagram tirẹ naa lai gbe lẹyin ẹnikan ṣugbọn to n fi apẹrẹ bo ṣe yẹ ki ọrọ maa rin laarin awn oṣere han.

Lara awọn gbajugbaja oṣere to tun ti da si ọrọ lati lati gbiyanju pipari ẹ ni Alhaji Yinka Quadri, Idowu Phillips to ni "Àwa kìí jà lásìkò tiwa, ta ló bí ẹ tí wàa máa jà? - Iya Rainbow".

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption‘Tunde Kelani yan mi jẹ lori fiimu ‘Toluwanilẹ’
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTunde Kelani; Èmi ò jẹ́ Baba Wande ní owó lórí fíímù Tolúwanilẹ̀

Yomi Fabiyi naa kẹnu bọ ọpọlọpọ ọrọ lati rọ awọn mejeji ki wọn wa bi wọn yoo ṣe yanju ẹ.

Ni ti agba oṣerebinrin, Fausat Balogun ti gbogbo eniyan mọ si Madam Saje sọ fun awọn oniroyin pe ni ni toun o "mi o fẹ da si ija to wa laarin Toyin!".

Nigba ti akọroyin BBC Yoruba kan si i, ti wọn si ba ọrọ de ibi ija Toyin Abraham ati Lizzy Anjorin, esi ti Madam Saje fọ ni wi pe "Haa, mo dẹ wa wa lori itage lọwọ lọwọ bayii o, ẹ pe mi pada ni bii wakati meji".

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKunle Afolayan: èmi kò fẹ́ fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ mi

Awọn iroyin mii ti ẹ le nifẹ si