Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ogun ti kéde ìbẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́

Gomina Abiodun ti Ipinle Ogun
Àkọlé àwòrán,

Gomina Ipinle Ogun

Ijọba ipinlẹ Ogun ti sọ eto ẹkọ di ọfẹ fun awọn ọmọ alakọbẹrẹ ati ti girama.

Gomina Ipinlẹ naa, Dapọ Abiodun, lo sọrọ yii nigba ti oun ba awọn ẹni ọrọ kan sọrọ.

Dapọ Abiodun ni opin ti de ba inira ti awọn obi n koju lati le san owo ile iwe awọn ọmọ wọn.

Nigba ti ikọ ile isẹ BBC Yoruba n ba abẹnugan gomina naa Kunle Abiodun sọrọ ni alaye naa ti jẹyọ.

O tẹsiwaju wi pe ẹgbẹrun mẹrin din diẹ owo naira ti awọn obi n san ti di ohun itan ni ipinle naa.

Gomina naa wa pa laṣẹ pe, ko si ile iwe kan ti o gbọdọ gba owo lọwọ akẹkọọ kan mọ lati asiko yii ni ipinlẹ naa.

Ninu ọrọ rẹ, o ni wọn ti gbegi le sisan owo ile iwe ni ipinlẹ Ogun lasiko yii.