Amnesty International; Ìjọba Nàìjíríà kò lẹ́tọ́ lati tẹ ẹ̀tọ́ Ṣòwòrẹ́ mọ́lẹ̀

Omoyele Sowore
Àkọlé àwòrán O to gee

Ajọ kan to n ri si ibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International ti koro oju si awọn ẹsun igbimọpọ lati ditẹ gba ijọba ti wọn fi kan oludije fun ipo aarẹ nigba kan ri lorilẹ-ede Naijiria, Ọmọyẹle Ṣoworẹ.

Ajọ Amnesty international ṣalaye pe ọna ati fi ẹtọ Ṣoworẹ dun un ni njọba n yẹ.

Amnesty international ni awọn ẹsun ti ko lẹsẹ n lẹ ti wọn fi kan Ṣoworẹ jẹ ara ọgbọn ti ijọba apapọ n da lati fi ẹtọ rẹ dun un.

Bakan naa ni wọn ni bi ijọba ṣe tii sinu ahamọ labẹ ikawọ ofin to de iwa igbesunmọmi nitori pe o ṣe amulo ẹtọ rẹ labẹ iwe ofin jẹ ara aṣilo ọna lati fi ofin di ẹnu awọn to ba n tako ijọba ni.

Wọn wa ke sawọn alaṣẹ lorilẹ-ede Naijiria, 'lati bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan ki wọn maa si lo awọn ofin naa lati tẹ oju ẹto Ṣoworẹ mọlẹ."

Image copyright Sahara reporters

Ijọba apapọ ṣi iwe ẹsun fun Ọmọyẹle Ṣoworẹ ti wsn si fi ẹsun kan an pe o gbimọran ati gbimọpọ idtẹ gba ijọba nipa agbekalẹ eto iwọde Revolution now ni ọjọ karun oṣu kẹsan ọdun 2019 lati ys aarẹ orilẹ€de Naijiria nipo.

Agbẹjọro agba lorilẹ-ede Naijiria to tun jẹ minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami, SAN lo ṣe eto ifisun naa.

Kini awọn eniyan Naijiria n sọ lori ọrọ yii?

Ero awọn ọmọ Naijiria ṣotọọtọ lori bi ijọba Mohammadu Buhari ṣe ti Omoyẹle Soworẹ mọle lati ọkan le ni adọta ọjọ sẹyin.

Awọn kan n yin Arẹ Buhari pe o fẹ tete pẹka iroko sowore ni, ko too maa gbẹbọ lọwọ Naijiria:

Bee naa ni awọn miran ni ori bibẹ kọ ni oogun ori fifọ Sowore lasiko yii:

Ọpọ ọmọ Naijiria gba pe asiko ti to ki ijọba tu gbogbo awọn to wa ni ahamọ silẹ nitori ominira lati sọrọ to yẹ ko wa ni Naijiria.

Àkọlé àwòrán O to gee

Loju awọn miran bii Kayode Ogundamisi, ẹsun meje ti ijọba fi kan Omoyele to dije dupo aarẹ ninu idibo Naijiria to kọja ti pọju:

Nigba ti awọn bii Don Jazzy ni ọna lati di awọn to n sọrọ lodi si aṣiṣe ijọba Buhari lẹnu ni atimọle Sowore jẹ lasiko yii

Bẹẹ naa dẹ ni awọn miran gba Sowore nimọran lati san sokoto rẹ ko le daadaa nitori ẹsun ifọtẹgbajọba ti ijọba fi kan an

Awọn miran gba pe ohun ti Sowore ṣe ko dara rara:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood: Kò sí ẹni ti òbí mi kò lè sọ̀rọ̀ sí -Sisi Quadri