Marriage Proposal: Ikú mú Steven tó lọ ẹ́nu ìfẹ́ kọ olólùfẹ́ rẹ̀ lábẹ́ omi lọ

Image copyright @Antoine
Àkọlé àwòrán Ọrọ ifẹ bii adanwo ni

Oriṣiriṣi ọna ni awọn ololufẹ n gba lati fi dẹnu ifẹ kọ ara wọn ni aye ode oni.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ṣe o o maa tẹle mi titi aye ni ibudo itaja, ni awọn miran n dẹnu ifẹ kọ ara wọn lori ayelujara ati lọna miran.

Steven Webber ati Kenesha Antoine ni ololufẹ meji ti ọrọ wọn di akakọgbọn lasiko yii kaakiri gbogbo agbaye.

Omo ilẹ Amẹrika ni Steven Webber to dẹnu ifẹ kọ Antoine lasiko isinmi wọn ni ile itura Manta Resort ni erekuṣu Pemba ni orilẹ-ede Tanzania.

Ninu fọnran fidio ti ololufẹ rẹ, Kenesha Antoine ka lati fi maa ṣe iranti ọna ara ọtọ ti Steven fẹ fi dẹnu ifẹ irinajo titi lae han.

Fidio yii ṣafihan bi Steven ṣe kọkọ bẹ somi to mu beba akọsilẹ awọn ọrọ ifẹ to fi dẹnu kọ Antoine dani ki ọlọjọ to de.

Koda oruka, idana to jẹ afihan mo gba lati maa ba ẹ lọ wa lọwọ Steven ko to di ero alakeji.

Image copyright @Kenesha
Àkọlé àwòrán Kenesha ati Steven, iku omi lo n pa omuwẹ!

Kenesha lo lo kọkọ ke gbajare to fi kigbe sita pe ololufẹ oun ti dero alakeji ki awọn eeyan to gbee sita.

Alaṣẹ, Manta Resort, Mathew Saus ti BBC fi ọrọ wa lẹnuwo lori iku ọgbẹni Weber ni iṣẹlẹ naa ba ẹni ninujẹ gidi ni.

O ni o mi gbogbo awọn eniyan ile itura naa pe bawo ni ọrọ ifẹ ṣe wa maa n mu iku dani.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTani otutu ma n mu ju laarin Ọkunrin ati Obinrin?

Ogbeni Saus ni kete ti Kenesha pariwo sita lati inu omi ni awọn oṣiṣẹ ile itura naa ti dide iranlọwọ ṣugbọn ti ẹpa ko boro mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYaa Asantewaa: Ti ẹyin ọkunrin Ashanti kò bá tẹsiwaju, awa obinrin yóò lọ

Bawo ni ọrọ ifẹ ṣe wa di ọrọ iku lọsan gangan?

Ọjọ mẹrin ni awọn ololufẹ mejeeji yii sanwo ẹ lati lo nile itura naa ni iyara tomi wa ni abẹ rẹ.

Nigba ti o di ọjọ kẹta ti wọn ti de sile itura yii ni Steven gbiyanju lati dẹnu ifẹ ayeraye kọ Antoine ki o to gba ekuru jé lówọ ẹbọra.

Steven wo awo oju ninu omi ati bata wiwẹ lodo, o mu beba fifi ifẹ rẹ hanni oju ferese loke omi naa ni eyi ti ololufẹ rẹ n ka si fọnran fidio.

Image copyright @Kenesha
Àkọlé àwòrán Ekurọ ni alabaku ẹwa ni ọrọ ifẹ Steven

Akọsilẹ to wa ninu beba ti Steven fi fi ifẹ han si Antoine ni: Mo kọ lati sé eemi, mo ṣetan lati sọ nipa ifẹ mi ni kikun fun ẹ, Ko si aaye fun mi lati sọ ohun gbogbo ti mo nifẹ nipa ẹ fun ẹ Ṣugbọn... gbogbo nkan ti mo fẹran nipa rẹ, ojoojumọ ni mo fi n nifẹ rẹ sii.

Ninu atẹjade ti Antoine fi soju opo facebook ẹ lo ti ṣafihan idahun ti oun fẹ fun Steven pé: Bẹẹni! mo gba lati fẹ ẹ ni igba milọnu!.

Antoine ni o dun oun pupọ pe awọn ko le jọ ṣajọyọ ifẹ awọn papọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood: Kò sí ẹni ti òbí mi kò lè sọ̀rọ̀ sí -Sisi Quadri

O ni inu oun dun pe awọn jọ ni ajọṣepọ to dun ni igbẹyin aye rẹ nibi isinmi ti wọn lọ ni orilẹ-ede Tanzania.

Ileeṣẹ orilẹ-ede Amẹrika to n risi ọrọ awọn ọmọ ilẹ Amerika fidi iku Steven mulẹ pe lootọ lo ti doloogbe ni Tanzania, ni ila oorun ilẹ Africa.

Ijọba Tanzania ba wọn kẹdun pe ki Olorun dẹ ile fun ololufẹ yii.