World Event: Wo ohun tó ṣelẹ̀ ní àgbáyé lọ́sẹ̀ tó kọjá

Kíni Donald Trump, Mohammadu Buhari, Awọn olóró Isẹyin àtàwọn míì ṣe lagbaye láàrin ọ̀sẹ̀ tó kọja?

oloro

Oríṣun àwòrán, @Oyo matters

Àkọlé àwòrán,

Awọn olórò lasiko ọdun oro ni ilu Isẹyin nipinlẹ Oyo. Ọdun oro yii waye ni 5:30 irọlẹ si 5:30 idají. ọdun oro jẹ ọkan lara ọdun iṣẹṣẹ ilẹ Yoruba

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán,

Diẹ lara awọn oluranlọwọ ti wọn de si Floriana ni Malta lasiko ti awọn ọmọ ogun ilẹ Italy n sin wọn lọ.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Meji ninu awọn \pmọ ogun Calvary ti ile Oba Dutch lasiko ayẹyẹ iranti iṣoro ayipada oju ọjọ lagbaye. Eto yii waye ni Scheveningen nitosi Hague.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Alaṣẹ Luxemburg, Xavier Bettel ṣafihan ero rẹ ni kikun lasiko to n ṣe ipade pẹlu awọn akọroyin. eyi waye lẹyin ipade rẹ pẹlu Boris Johnson. Johnson wọgile apero rẹ pẹlu awọn akọroyin nitori pe ọpọ gba pe ẹru baa, ki wọn ma lọ pariwo lee lori.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Eyi ni aworan apa kan nibi ina to n jo ni ìgbẹ́ Amazon ni Rio Pardo ni orilẹ-ede Brasil. Awọn panapana kan ni wọn ya aworan awodamiẹnu ina to n jo ni papa yii.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Donald Trump, aarẹ Amẹrika ree lasiko to n wọ baalu Air Force tawọn ọmọ ogun lasiko irinajo rẹ. Trump n wọ ọkọ ofurufu ti aarẹ Amerika yii lọ si California.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Awọn eniyan Almoradi ni ẹkun Costa Blanca ree ti wọn duro ti ẹru wọn lẹyin iji lile lasiko arọọrọda ojo to rọ lọsẹ to kọja

Oríṣun àwòrán, @folasade

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Mohammadu Buhari yan Omowe Folasade Esan dipo Winnifred Oyo Ita Giwa. Oun ni yoo maa dari ẹka awọn oṣiṣẹ ọba ni Naijiria gẹgẹ bi adele. Fasiti Ibadan ti sanmọnti gbe dunlẹ lo ti kawe gboye lọdun 1987

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Aworan to jọju yii lo ṣafihan agba eranko abiwo gaaraga yii to n rẹ oungbẹ ni papa Richmond ni iwọ oorun guusu London.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán,

Ọkunrin kan ni yii to n rin lọ lẹgbẹ aworan ipolowo ọja kan lẹgbẹ ogiri. Ti ẹ ba wo aworan yii lakọkọ, ẹ maa ro pe ọwọ nla kan fẹ ji arakunrin naa gbe ni.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán,

Greta Thunberg to jẹ ajijangbara lori itọju ayika n ya fọto pẹlu Militza Flaco. Flaco naa jẹ ajijangbara ayika ni Panama. Iwaju kootu ile ẹjọ to gha julọ ni Amerika ni wọn ti ya awọran naa ni Washignton DC to jẹ olu ilu America.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Gbajugbaja Bjorn Ulvaeus ti awọn onirinṣe ori=in Abba Orchestra naa mura bii ti aye atijọ 1977. O mura bẹẹ laisko eto Mamma Mia ni gbọngan O2 ni London