Africa Events: Ilẹ̀ Afrika lọ́sẹ̀ yìí nínú àwòrán!

Láti Tunisia lọ si Zimbabwe ti a ti sìnkú Robert Mugabe títí lọ sí ọ̀dọ̀ ìyá ẹlẹ́ja àsun ni Kenya, ẹ fun ojú lóúnjẹ ayọ̀.

obinrin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Idibo yan aarẹ tuntun ni orilẹ-ede Tunisia waye lọsẹ to kọja. Obinrin kan ni yii to n fayọ han lẹyin to dibo yan ẹni to wuu. Aro lori eekana ika ọwọ yii lo ṣafihan ẹni to ti dibo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ogun ilẹ to duro wamu lẹnu iṣẹ ni Sousse ni orilẹ-ede Tunisia. Awọn agbofinro parapọ ṣiṣẹ lati pese eto aabo to peye fawọn eeyan lasiko idibo to kọja ni Tunisia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awa ara wa la rira wa, ologinni lo rọmọ ẹkun! Adut Akech to jẹ arinrinoge South Sudan pade Naomi Cambell ikeji rẹ lati England. Iṣẹ ori ran wọn ni wọn jọ n ṣe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ẹja jẹ aayo ọpọ eniyan kaakiri agbaye. Iya ẹlẹja kan ni yii ni Nairobi lolu ilu Kenya. Iya yii n ta asun ẹja ni ọja ẹja oriṣirisi ni Nairobi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ẹni kan kii jẹ awa de!. Awọn oniṣegun oyinbo ni Harare ti bẹrẹ iyanṣẹlodi lati igba ti awọn oṣiṣẹ eleto ilera nile iṣẹ aarẹ ti padanu iṣẹ wọn. Lọjọru to kọja ni dokita yii lọ ba awọn agbofinro to n ṣo ile aarẹ sọrọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn agbofinro duro wamu lẹnu iṣẹ ni Quagadougou. Lọjọ Aje ni wọn pese eto aabo fawọn to n ṣe iwọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ero lo pejọ pọ ni Liberian City ti Monrovia. Lojọru ni wọn ti n duro de aarẹ wọn lasiko isinku awọn panapana. Awọn panapana mẹtadinlọgbọn lo gbẹmi mi ni ile ẹkọ Kurani. Awọn ọmọde lo pọju ninu awọn to dero ọrun naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lọjọ Aje ni awọn eniyan Zimbabwe rirnin ikẹyin fi ṣaponle aarẹ wọn nigba kan ri, Robert Mugabe. Ojo kẹfa, oṣu kẹsan an, ọdun 2019 ni Robert Mugabe gbẹmi mi lẹni ọdun marundinlọgọrun un. Awọn neiyan Zimbabwe n ṣelede lẹyin Mugabe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Murombedzi ni wọn gbe oku aarẹ Robert Mugabe lọ si itẹ. O to iwọn kilomita mẹtadinlaadọfa ni Harare. Ibi yii ni wọn tẹ oku Robert Mugabe si ṣaaju isinku rẹ ki awọn ololufẹ rẹ le ri.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Grace aya Robert Mugabe dagbere igbẹyin fun ọkọ rẹ. Iku wọle mu Robert lọ ṣaaju irinajo wọn lojo keji. Ni papa iṣere National Stadium ni Grace ti dagbere igbẹyin fun ọkọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, @sowore

Àkọlé àwòrán,

Omoyele Sowore, okan lara awọn ọdọ to dije dupo aarẹ Naijiria ninu eto idibo to kọja ti wa lati mọle ijọba. Oni lo pe ọjọ kejilelaadọta ti ọwọ ofin ti muu. ẹsun meje ni wọn fi kan an pe o fẹ ditẹ gbajọba Naijiria. Opo awọn ololufẹ rẹ lo bọ sita ṣe iwọde E tu Sowore silẹ lọsẹ to kọja.