Ikọ̀ ọmọogun Naijiria ti kéde ‘Operation positive identification’!

'Operation Positive Identification'

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ikọ ọmọogun òfúrufú Naijiria pàrọwà sí àwọn ènìyàn ní ìhà Àríwá láti má a gbé àmìn ìdánimọ̀ wọn dání.

Ikọ ọmọogun orilẹede Naijiria ti bẹrẹ 'operation positive identification’ lati koju ikọ Boko Haram to ti ṣe ikọlu si ọpọlọpọ eniyan ni ẹkun ariwa orilẹede Naijiria.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Ado Isaikọ ọmọ ogun Naijiria gbe jade, ikọ naa wi pe ẹnikẹni ti ko ba ni Iwe idanimọ orilẹ-ede Naijiria ni agbegbe naa yoo wọ gau.

Ọmọogun Naijiria ni ọna yii yoo fun ikọ ọmọ ogun laaye lati mọ awọn ti wọn jẹ agbesunmọmi ati janduku ni agbeegbe naa.

Lara awọn iwe idanimọ ti eniyan gbọdọ ni ni Kaadi idanimọ orilẹ-ede Naijira, Kaadi Iforukọsilẹ fun idibo, Iwe irinna ọkọ ati iwe irinna ilẹ okeere.

Atẹjade naa fikun wi pe awọn ọmọ ogun yoo bẹrẹ iwadii lori ẹnikẹni ti ko ba ti ni Iwe Idanimọ rẹ ni agbegbe naa.

Ikọ ọmọ ogun Naijiria wa kesi awọn ara ilu lati fi ọwọ sowọpọ pẹlu wọn, ki alaafia le jọba ni agbegbe naa.