Afenifere: A kò lè gbà kí ọlọpaa daṣọ àrán bo ọ̀rọ̀ yìí mọ́lẹ̀

Image copyright Police facebook
Àkọlé àwòrán Awọn agbofinro ko gbiyanju to ninu iwadii yii

Ẹgbé Afénifére kọminú lórí ìwádìí ikú ọmọ Baba Faṣọnnranti to jẹ olori Afẹnifẹre- Odumakin

Ẹgbe Afenifẹre ti fi ero wọn han lori aijafafa ajọ awọn ọlọpaa lori ẹni to pa Arabinrin Funkẹ Ọlakunrin.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ naa, Yinka Odumakin fi ṣọwọ si awọn akọroyin ni ọjọ Isinmi Osẹ yii.

Wọn ni Ọlọpaa ti n fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa ti wọn ko i si ti ri ẹni to pa arabinrin naa titi di asiko yii.

Odumakin wi pe o ti le ni osu meji bayii ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ti ko si aridaju pe ajọ Ọlọpaa ti ri ẹnikẹni mu lori ọrọ naa.

Ṣe arabinrin Olufunkẹ Ọlakunrin ti o jẹ ọmọ aṣiwaju ẹgbẹ Afẹnifẹre, Rauben Faṣọnranti, ni awọn agbebọn pa ni popona Ọre si ilu Eko.

Ẹni ti o jẹ aburo si oloogbe naa, Kẹhinde Faṣọnranti ti sọ tẹlẹ nigba ti iṣẹlẹ naa waye pe awọn ọlọpaa ni darandaran lo ṣeku pa arabinrin naa.

Ẹgbe naa ni ọkan ninu awọn ẹri pe Ọlọpaa ko ṣakitiyan ni pe, wọn tete yanda ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn pa arabinrin naa si fun ẹbi rẹ.

Gẹgẹ bi wọn ti wi, wọn ni Ọlọpaa ko ṣe iwadii kọkan lọwọ awakọ to wa arabinrin naa titi di asiko yii.

Bakan naa, abajade ayẹwo lori bi iku naa ṣe jẹ ko i tii tẹ ẹbi naa lọwọ titi di asiko yii.

Ẹgbẹ naa wa n rọ gbogbo awọn ẹni tọrọ kan lati parọwa si ọlọpaa ki wọn o tete fi oju awọn ẹni ibi naa lede ni kiakia.

Image copyright olufunke facebook page
Àkọlé àwòrán Ibanujẹ dori agba kodo, ki Olorun tu ẹni ti ọrọ kan ninu.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood:Ṣàgbẹ̀lójú yòyò ni ọ̀ps àwọn òṣèré- Ojopagogo