Oyo Tax -Àwọn ilé ìjọsìn,Mọṣaláṣi kò ní san owó ori lọyọ

Image copyright Makinde facebook
Àkọlé àwòrán Gomina Seyi Makinde

Gomina Ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde ti wi pe ile ijọsin ati Mọṣalaṣi nikan ni ko ni san owo ori mọ.

O sọrọ yii ni opin ọsẹ nibi idupẹ ayẹyẹ aadọrin ọdun Bisọọbu ijọ Aguda ti ipinlẹ naa, Gabriel Abegunrin ninu ijọ Ascension,ni Bodija.

Oluranlọwọ pataki fun gomina, Idowu Ogedengbe to ṣoju rẹ lo sọrọ naa wi pe, ijọba ti gbegi le sisan owo ori awọn ile ẹlẹsin ni ipinlẹ naa.

O ṣalaye wi pe, igbesẹ naa tako ipinnu ijọba ana ni ipinlẹ naa pe ki awọn ile ẹlẹsin maa san owo ori lati gbe eto abo lẹsẹ.

Ninu ọrọ Gomina Seyi Makinde ṣalaye pe irufẹ ile ijọsin to ba ni ile iwe, tabi ti wọn n daṣẹ silẹ yoo san owo lori iru ile iṣẹ bẹẹ lai fọrọ ṣofun.

Makinde tan imọlẹ sori ọrọ to n mu awuyewuye wa lori owo ori sisan ni pataki idaṣẹ silẹ awọn ile ijọsin.

Ṣaaju ni Ijọba Abiọla Ajumọbi ni ipinlẹ Oyo ti fi ṣe kan an nipa fun ile ijọsin lati san owo ori fun atilẹyin eto aabo lasiko ijọba to kogba wọle nibẹ.

Ọọni ti ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan ti Ọba Fayẹmi Olumuyiwa ṣaṣoju fun naa wa ni ibi ayẹyẹ naa ti Aarẹ awọn ijọ Aguda, Augustine Akubueze naa ko gbẹyin.

Related Topics