Ondo Cow Death: Àrá sán pa Màálù mẹrìndínlogojì ní ìpínlè Ondo

Awon Maluu ti Ara Sanpa Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Oku Maluu ti Ara sanpa

Ko din ni Mẹrindinlogoji maalu to ku iku ojiji ni ipinlẹ ondo ni opin Ọsẹ to kọja yii.

Iṣẹlẹ yii waye ni ilu Ijarẹ ni ẹgbẹ Ilaramọkin ni ijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ ni Ipinlẹ Ondo nigba ti ara nla kan san lataari ojo to rọ lasiko naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo Cow Death: Àrá sán pa Màálù mẹrìndínlogojì ní ìpínlè Ondo

Ilu Ijarẹ jẹ ilu ti wọn ti ni ifẹ si iṣẹ obì gbingbin ti o si ni ori Oke kan ti a n pe ni Ọwá nibi ti ẹni kankan kii deede gun.

Iwadii fihan pe, Ọba ilu naa ati awọn wundia nikan ni o ni le gun ori Oke Ọwá naa, sugbọn ti awọn maalu naa gun ti wọn si ku sibẹ.

Wọn ni ẹẹkan lọdun ni Ọba ilu yii maa n lọ ori Oke yii ti o si jẹ oke ti o tobi julọ ninu ilu naa.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ori oke ti awọn wundia n gun naa ni yii

Iwadii tẹsiwaju pe, lati ibẹrẹ Oke naa titi de opin rẹ ko din ni irin wakati kan gbako.

Oloye Wẹmimọ Ọlaniran to jẹ igbakeji Ọba Olujare ti ilu Ijare ṣalaye pe bi awọn maluu naa ṣe de ori oke naa jẹ kayeefi.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ori oke ti maalu gun yii ki i se ori oke lasan rara

Oloye Ṣapetu ti ilu Ijarẹ ni ibi Oriṣa ilu ni Ori Oke yii jẹ fun ilu Ijare bnitori pe, ti Ọba ba lọ, yoo lo odindi ọjọ kan nibẹ lati fi ṣetutu ko to pada sọkalẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood:Ṣàgbẹ̀lójú yòyò ni ọ̀ps àwọn òṣèré- Ojopagogo

Oloye naa ni wi pe gbogbo awọn ti o ti tẹ oju ilẹ mọlẹ bi iru eyi sẹyin ni oju wọn maa n ri iru nkan bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood: Kò sí ẹni ti òbí mi kò lè sọ̀rọ̀ sí -Sisi Quadri