UN General Assembly: Àwọn ìdí pàtàkì tí ààrẹ Buhari fi gbọdọ kópa rèé

Image copyright Omoboriowo
Àkọlé àwòrán UN General Assembly: Àwọn ǹkn pàtàkì tí ààrẹ Buhari fi gbọdọ kópa rèé.

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàijiria Muhmmadu Buhari tí rìnrìn ajo lọ si lọ́jọ́ Aìku ló si orilẹ̀-èdè Amerika níbi ìpàdé àpàpọ gbogbo orilẹ̀-èdè ẹlẹkẹ́rinléláàdorin iru rẹ̀.

Ìpàde náà ṣe pàtàkì sí orilẹ-èdè Naijiria àti ààrẹ Buhari nítori pé ọmọ Naijiria ti wọ́n ṣẹṣẹ̀ yàn gẹ́gẹ́ bi ààrẹ àjọ náà ní ọjọ díẹ̀ sẹyin.

Àra ǹkan ti wọ́n yóò foju to nibi àpérò náà, ni láti koju ìjà sí òṣì àti àìní, pípèsè ètò ẹkọ àti láti gbé ìgbésẹ̀ lóri ọ̀rọ̀ ojú ọjọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood: Kò sí ẹni ti òbí mi kò lè sọ̀rọ̀ sí -Sisi Quadri

Ètò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà yóò bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ kẹrinlélogun, oṣù kẹsan an, níbi ti àwọn adari yóò ti maa jiroro lori àkori àpéro ọdun yiìí.

Image copyright Bayo Omoboriowo
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Buhari àti gomina ìpínll Osun Oyetola kọwọrinnlọ Amerika

Ààrẹ Buhari ni àdári káarun ti yóò sọ̀rs nibi ìpàdé àgbàyé náà.

Ìgbàkeji rèé ti ọmọ Naijiria yóò gba ìpò ààrẹ UN, ní ọdun 1989 ni ọmọ Niajiria kan jẹ ọmọ oogun Joseph Garba.

Níbi ìpàde náa ààrẹ Buhari yoo nilo láti sọ ìpa ti Nàijiria ti ko àti ibi ti o ba iṣẹ́ de, pàápàá jùlọ lóri gbogbo iléri to ti ṣe lásìkò ipolongo láti dupo ààrẹ lọdun 2015 àti 2019.

Èyí mọ didoju ìwà àjẹbánu bolẹ àti mímú ìdàgbàsoké ba ètò ọ̀r ajé Naijiria.