Yollywood: Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun fún mi - Toyin Afọlayan

Toyin Afọlayan Image copyright @telesquib
Àkọlé àwòrán Orin Baba modupẹ ni Toyin Afọlayan nkọ loni ọjọ ibi rẹ.

Toyin Afọlayan ti gbogbo eeyan mọ si Lọla idi jẹ ẹ ni wọ ki ilu mọ oṣere tiatia Yoruba.

Wọn bii ni ọjọ kẹrinlelọgbọn, oṣu kẹsan an, ọdun 1959, ni Agbamu, ni ijọba ibilẹ Irẹpọdun ni ipinlẹ Kwara ni aarin gbungbun Naijiria.

Agbamu yii ni ilu Samuel Adedoyin to jẹ ogbontarigi oniṣowọ Agbamu ni Kwara ko too re ibi agba n re.

Loni ni Toyin pe ẹni ọgọta ọdun lori oke eepẹ.

Oun ni aburo baba gbajugbaja oṣere tiata ni, Kunle Afọlayan.

Irawọ Toyin bu jade lagbo oṣere sinima lẹyin to kopa gẹgẹ bii Madam Adisa, ninu eree ti akọle rẹ n jẹ "Deadly Affair" to jade lọdun 1995.

O tun kopa ninu awọn ere miran to gbajumọ, bii Oṣunwọn Ẹda ti wọn ṣe lọdun 2006, Ajẹ Mẹtta to jade lọdun 2008, Iṣẹ Oniṣẹ to jade lọdun 2009, Madam Yoyo lọdun 2004, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Toyin bẹrẹ iṣe oṣere nipasẹ ẹgbọn rẹ, ti oun tikara rẹ jẹ oṣere tiata, Adeyẹmi Afọlayan ti gbogbo eeyan mọ si Ade Love.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

Gbajumọ oṣere yii ko ni iṣe tabi owo miran lẹyin iṣẹ tiata.

Oṣere yii ni ọmọ obinrin mẹta, bi o tilẹ jẹ pe ọmọ okunrin kan ṣosọ to ni ti fi ilẹ ṣaṣọ bora ni awón ọdun diẹ sẹyin.

Bẹẹ ni o tun jẹ opo.

Image copyright Instagram/lolaidijeafolayan
Àkọlé àwòrán O ni oun ko roo ti tẹlẹ ri lati jẹ oṣere, sugbọn ori lo mọ ibi ẹsẹ n gbeni re

Ninu awọn ere to ti ṣe sẹyin, o ma n kopa bi onojọgbọn obinrin, sugbọn ninu ifọrọwwerọ kan lo ti sọ pe ara oun ko gbona, afi ninu ere agbelewo nikan ni gẹgẹ iṣe ti oun yan laayo.

Toyin Afọlayan jẹ elesin Kristẹni ti ọpọpọlọpọ awọn oṣere kekeke si n wo loke gẹgẹ bi aṣaju rere.

Bi o tilẹ jẹ pe o ṣe aṣeyọri ninu iṣe to yan layo gẹgẹ bi oṣre, o ni oun ko roo ti tẹlẹ ri lati jẹ oṣere, sugbọn ori lo mọ ibi ẹsẹ n gbeni re.

Ninu ọrọ to fi lede loju opo Instagram rẹ larọ yii, Toyin dupẹ lọwọ Ọlọrun to da ẹmi rẹ si di ẹni ọgọta ọdun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌjẹ̀bú: Àgbàlàgbà ni mo máa ń ṣe nínú eré tẹ́lẹ̀

Lọla jẹ ọkan lara àwọn obìnrin kan tí wọ́n máa ń ṣe ipa ẹni tí kò gba ìgbàkugbà nínú eré.

Eré Obìnrin Àsìkò tí olóògbé Alade Aromire ṣe ni Toyin Afolayan ti rí ìnagijẹ rẹ̀ tíi ṣe Lola Idijẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSport Betting: Idí rèé tí àwọn ọ̀dọ́ kan fi n ta tẹ́tẹ́...

Loni, ayọ olọjọ ibi naa kun pupọ.

O fi orin awo ọpẹ si ẹnu pe oun pe ọgọta ọdun l;ori oke eepẹ.

O ni "Baba modupẹ, lati ori mi de isalẹ, iṣẹ ọwọ rẹ ni baba mo dupẹ. Mo ki ara mi ku ọjọ ibi."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood: Sinimá Ajé Ọjà tún so Fathia àti Saheed Balogun pọ̀ nínú Sinimá