Niger Delta: kò tún sí rògbòdìyàn mọ ní agbègbè epo rọbì láti àsìkò yii lọ

Tayo Alasoadura Image copyright @Alaso Adura
Àkọlé àwòrán Gbogbo Ise Asepati ni yoo di mimu ṣẹ

Minisita kekere fun agbegbe Niger Delta, Senatọ Tayọ Alaṣọadura ti ni ki awọn ọmọ Orilẹ-ede yii maa reti didun ti Ọsan yoo so.

Dayọ Joseph, to jẹ olubadamọnran rẹ lori ọrọ iroyin lo sọ ọrọ yii fun BBC Yoruba lasiko to n sọrọ ipo tuntun ti Alaṣọ adura.

O sọrọ kikun lori igbesẹ ajọ Naija-Delta lati dẹkun rogbodiyan agbegbe naa.

Alaṣọ Adura ni ijọba ti ṣetan lati tẹ awọn ọdọ ẹkun yii lọrun lori ohun gbogbo ti wọn n fẹ nipa ṣiṣẹ e lasiko.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria ni ẹnu ya lana nigba ti aarẹ Buhari kede paṣipaarọ laarin awọn minista meji Ṣé Festus Keyamo ni yóò yanjú aáwọ̀ lórí owó òṣìṣẹ́ ni?.

Alaṣọ Adura to jẹ minista abẹle ti Buhari yan fun ọrọ awọn ọṣiṣẹ loṣu to kọja ni wọn paarọ ipo rẹ si minista abẹle lori ọrọ ẹkun Naija-Delta bayii.

Festus Keyamọ lo lọ ropọ rẹ lẹyin paṣipaarọ naa.

Agbenusọ Minista abẹle tuntun fun ọrọ Naija-Delta tẹsiwaju pe gbogbo rogbodiyan ni agbegbe naa yoo di afiseyin tegun nfiṣọ lati saa yii lọ.

Agbenusọ Alaṣọadura ko ṣai mẹnu ba a wi pe gbogbo iṣẹ aṣepati ni yoo di mimu ṣe ni gbogbo agbegbe ti wọn ti n wa epo rọbi ni orilẹ-ede yii.

Nipa riro awọn ọdọ lagbara, Alaṣọadura wi pe asiko naa tito lati mu inu awọn ọdọ dun, ti opin yoo de ba gbogbo kudiẹkudiẹ naa.

O wa fi da awọn eniyan agbegbe naa loju pe ljọba yoo pese owo fun ipinlẹ kọọkan lati le ṣiṣẹ to kun oju oṣunwọn.

Dayọ Joseph tun ni ki gbogbo eniyan lpinlẹ Ondo fi ọkan balẹ pe Alaṣọ Adura yoo jẹ aṣoju rere ti yoo si mu igbega ba tolori tẹlẹmu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBrazil Yoruba: A n gbé àwọn ère Yorùbá káàkiri- Ọọni ti Ilé Ifẹ