Ondo Cow Death: Kò sí ẹnikẹ́ni tó leè wọ igbó oró tí àrá ti pa malu 36

Oku awọn malu naa Image copyright @todays_echo
Àkọlé àwòrán Igbo oro ni ori oke Ọwa ni ara ti san pa awọn malu naa

Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe ajakalẹ arun ko lee sẹyọ lẹyin ti ara san pa awọn maalu mẹrindinlogoji lori oke Ọwa ni ilu Ijarẹ.

Kọmiṣọna fun eto ilera ni ipinlẹ ọhun, Dokita Wahab Adegbenro lo sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba.

Adegbenro ni ijọba ti gbe igbesẹ pẹlu ileṣẹ eto ọgbin, lati fi oogun pakopako si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lọna ati dena ajakalẹ arun.

O ṣalaye siwaju sii pe "igbo oro ti iṣẹlẹ naa ti waye jina si aarin ilu, ti ko si ẹnikẹni to ma n lọ si ibẹ, eyi mu ko ṣoro ki ajakalẹ arun ti ibẹ wọ aarin ilu."

Wẹmimọ Ọlaniran, to jẹ Oloye Sapetu ilu Ijarẹ sọ fun BBC pe, ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣelẹ jẹ igbo oro ti ko si ẹnikẹni to ma n lọ ibẹ.

O ni ilu Ijarẹ yoo lọ ṣe etutu lati fọ ori oke naa mọ lẹyin ti ijọba ba ti pari iṣẹ wọn tan lori oke naa.

Image copyright Others

Dokita Bamidele Akinsorotan lati ẹka eto ọgbin ipinlẹ Ondo fi idi ọrọ naa mulẹ.

O ni gbogbo eto lo ti to lati lọ fi ogun pakopako si ori awọn maluu naa, sugbọn ileeṣẹ ọhun n duro ki awọn agba ilu Ijarẹ pari etutu ti wọn fẹ ṣe lori oke ọhun, ki wọn to bẹrẹ iṣe.

O wa rọ gbogbo ara ile Ijare lati ma bẹru, nitori ajakalẹ arun ko lee wọ aarin ilu lẹyin iṣelẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKí ni Yorùbá ń pe ọmọ tí wọ́n bí lẹ́yìn Àlàbá?