Dual Citizenship: Ilé Ẹjọ ni ìrètí mẹkúnnù - Aṣòfin Gboluga

Gboluga To Jawe Olubori Ni Ile Ejo Image copyright facebook page
Àkọlé àwòrán Gboluga Omo Ile Igbimo Asofin Kekere

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ni ilu Akurẹ ti da ẹjọ idalare fun ọmọ lle Igbimọ Aṣofun kekere ti wọn fi ẹsun kan.

Ni Ọjọbọ Ọsé yii ni ile ẹjọ kotẹmilọrun fi idi ibo to gbe Ikengbolu Gboluga mulẹ gẹgẹ bi olubori ninu eto ibo Oṣu keji Ọdun yii.

Ṣe ṣaaju ni ile ẹjọ ti fagi le ibo to gbe e wọle gẹgẹ bi Aṣoju agbegbe Irele/Okitipupa ni lpinlẹ Ondo latari pe o jẹ ọmọ Orilẹ ede United Kingdom.

Ajọ to n ri si Igbẹjọ Ibo ni o ti kọkọ gbẹsẹ le esi lbo naa ti wọn si kede ọmọ ẹgbẹ Oselu APC, Herbert Akintoye gẹgẹ bi Olubori.

Bakan naa ni Ajọ ti o wa fun eto Idibo ti fun Herbert Akintoye ni Iwe Eri ṣaaju,ṣugbọn ti ile ẹjọ ni ki wọn dapada fun Gboluga ni kiakia.

Ta ló léè bá Odun Adekola dù ú pẹ̀lú àwọn àmúyẹ yìí?

Osinbajo kò lẹ́tọ́ lábẹ́ òfin láti yọ amúnitì ara rẹ̀ - Amòfin Ajulo

Ẹ má fòyà! Kò leè sí àjàkálẹ̀ àrùn lẹ́yìn tí àrá sán pa màlu 36 - Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo

Ile Ejọ pa ẹnu pọ so wi pe ọmọ Orilẹ ede yii ko le e jẹbi didije fun eto ibo nitori pe o bere lati jẹ ọmọ orilẹ ede miran .

Ile Ejọ Kotẹmi lọrun naa wa da ile ẹjo kekere lẹbi igbese naa pe, ko yẹ ki wọn yọ Gboluga kuro ni Ipo ti wọn si ni ki o maa lọ ni idalare.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKí ni Yorùbá ń pe ọmọ tí wọ́n bí lẹ́yìn Àlàbá?