Yollywood: Awọn oṣere sinima ti wọn ti rinrin ajo ifẹ lẹẹmeji

Funke Akindele, Bukky Wright ati Foluke Daramola Image copyright others
Àkọlé àwòrán Orọ ifẹ bi adanwo lo jẹ fun takọtabọ

Ọrọ ifẹ lagbara kaakiri agbaye larin obinrin ati ọkunrin ti wọn ti balaga.

Lẹyin ti ọrọ ifẹ ti wọ tan ti ọkunrin gbe obinrin ni iyawo, Oriṣi nkan lo maa n fa gbọnmisii omi ko too laarin ololufẹ meji ni eyi ti ko yọ awọn oṣere Naijiria naa silẹ,

Oriṣirisi nnkan lo maa n ṣẹlẹ lagbo awọn oloṣere, bii ayẹyẹ iṣile, mọto rira, ija laarin ara wọn ati kikọra ẹni silẹ.

Kikọ ara ẹni silẹ yii maa n ṣẹlẹ laarin awọn oṣere tiata nilẹ yii ati loke okun nitori ko si ẹni ti iwa rẹ pe tan lagbaye.

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ nnkan lo maa n fa ikọra ẹni yii, ti aṣiri rẹ ko han si awọn ololufẹ elere agbelewo lọpọ igba.

Awọn oṣere yii naa ṣeeṣe ki wọn ṣalai gbadun irinajo ifẹ wọn ni igba akọkọ, ko jẹ pe ti wọn ba pade ẹlomii lẹẹkeji ni ọkan wọn ṣẹṣẹ maa balẹ sii.

Eyi to fihan pe, ko si igba ti eeyan ko le ri ayọ rẹ he ninu irin ajo ifẹ rẹ.

Diẹ lara awọn oṣere sinima Nollywood ti igbeyawo wọn tuka ti wọn si ṣe igbeyawo lẹẹkeji ki wọn to ri ayọ ni yii:

1. Funke Akindele:

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Funke Akindele tun ifẹ yan ki ọkan rẹ to bale

Funke Akindele ti di agba ọjẹ ninu ere agbelewo. Awọn ere bii Jenifa, Ekurọ, Aye olomo kan ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣafihan Funke lẹnu iṣẹ oojọ rẹ.

Ni ibẹrẹ pẹpẹ ni Funke kọ fẹ Almaroof Oloyede lọdun 2012, sugbọn tirela gba aarin wọn kọja loṣu keje, ọdun 2013 ti awọn mejeeji si fi ọrọ lede pe igbeyawọ naa ti tu ka.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFunke Akindele jẹ àkàndá ẹ̀dá - Adaku

Laipe sii ni Eledua tun da Funke lohun ti Abdulrasheed Bello, ti apele rẹ n jẹ JJC gbe e niyawo ni igba to ku diẹ ko pe ọmọ ọdun mọkandinlogoji ni ilu London.

Bayii Olorun ti fi ibeji ta Funke Akindele Bello lọrẹ Funke Akindele ti di ìyábejì pẹlu JJC to ti ni awọn ọmọ tẹlẹ ko to pade Funke Akindele.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ko si igba ti a da aso ti a ko rile fi wo

2. Foluke Daramola:

Arẹwa ati gbajumọ osẹre naa ni Folukẹ Daramọla to ti gbe ọpọlọpọ sinima Yoruba agbelewo sita.

O fẹ Tunde Sobowale lọdun 2005, sugbọn igeyawo naa tuka ni igba to di ọdun 2008.

Nigba to ba awọn oniroyin sọrọ lọdun to kọja, Foluke ni ohun to ba oun ninu jẹ ju lọ ni igba ti igeyawo oun akọkọ fori sọgi.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Foluke Daramola naa tun Kayode Salako yan leekeji

Sugbọn ni bayii, idunnu ati ayo loun fi n gbe nile ọkọ rẹ tuntun.

Folukẹ Daramola Salakọ gbagbọ pe o san ki ikọsilẹ waye ninu igbeyawo ju ki ẹni kan lọ pa ara rẹ danu tabi ki o maa foriti igbeyawo ti iwa ipá wa ninu rẹ lọ.

3. Bukky Wright:

Orukọ ọkọ akọkọ Bukky ni Gbeyega Amu, ti Ọlọrun si fi ọmọ meji ta wọn lọrẹ.

Sugbọn fun idi kan tabi omiran, igbeyawo naa tuka, lẹyin naa ni Bukky bẹrẹ ere ifẹ pelu Rotimi Makinde, to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣoju lọwọlọwọ.

Lai pẹ si asiko yii ni awọn kan tun gbe iroyin kan kiri lori ayelujara pe Bukky n fẹ gbajugbaja akọroyin ni, Femi Davies.

Image copyright @kindexgadgets
Àkọlé àwòrán Orukọ ọkọ akọkọ Bukky ni Gbeyega Amu, ti Ọlọrun si fi ọmọ meji ta wọn lọrẹ.

Sugbọn ẹmi ere ifẹ naa ko gun pupọ ni bi Bukky ṣe tẹsiwaju igbe aye rẹ.

Lẹyin naa lo tun fẹ Bolaji Saheed to jẹ ọkọ rẹ kẹrin, sugbọn tirela tun gba aarin wọn kọja.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Omo dara o dejo ni Bukky Wright ninu awon fiimu agbelewo Yoruba to dun

Lẹyin Saheed ni oṣere naa fẹ ọkọ rẹ ẹlẹẹkarun un, Adewale Onitiri to n fi ilẹ Amẹrika ṣebugbe, sugbọn o ṣeni laanu pe, iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe ko si ẹni to le sọ ni pato ohun to n ṣẹlẹ bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Isẹ́ Tíátà tí mò ń se ti tó mi jẹun'

4. Stella Damascus:

Ọkọ akọkọ to fẹ Stella to di oloogbe lọjọ kẹta, oṣu kejila, ọdun 2004 lo mu ko fẹ Emeka Nzeribe ni bonkẹlẹ lọdun 2007, sugbọn igbeyawo naa ko pẹ pupọ.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ko si igba tabi asiko ti eeyan ko le pade #eni bi #okan r#e

Lọwọ yii, Daniel Ademinokan ni ọkọ rẹ, ẹni to jẹ ọkọ Doris Simeon tẹlẹri.

Image copyright @Codedzone1
Àkọlé àwòrán Stella Damascus pẹlu ọkọ Doris Simeon tẹlẹ

Doris Simeon jẹ gbajugbaja oṣere ti oun ati Ademinokan bi ọmọkunrin kan fun ara wọn.

Stella ti ko lọ si Amerika bayii pẹlu Daniel Ademinokan. Awọn mejeeji n tẹsiwaju ninu igbeyawo wọn lorilẹ-ede Amẹrika.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀èdè Nàìjíríà sọ èrò wọn lórí Nàìjíríà

5. Clarion Chukwurah:

Wọ ki ilu mọ ni Clarion ninu iṣe osere lede oyinbo lorilẹ-ede Naijiria.

Lọdun 2003 ni igbeyawo rẹ pẹlu Tunde Abiola to fori sogi si iyalẹnu ọpọ awọn ololufẹ.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Wọ ki ilu mọ ni Clarion ninu iṣe osere lede oyinbo lorilẹ-ede Naijiria.

O tẹsiwaju lati fẹ Femi Oduneye ti awọn eeyan mọ si Femi Egyptian lọjọ ayajọ Valentine lọdun 2004, sugbọn igeyawo naa tun fori sogi loṣu karun un, ọdun 2006.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Wọ ki ilu mọ ni Clarion ninu iṣe osere lede oyinbo lorilẹ-ede Naijiria.

Nigba to di ọdun 2016 ni Clarion taa tan pẹlu ololufẹ rẹ, Anthony Boyd to n fi ile Amẹrika ṣebugbe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌjẹ̀bú: Àgbàlàgbà ni mo máa ń ṣe nínú eré tẹ́lẹ̀

6. Anne Njemanze:

Arewa Anne Njemanze lo fẹ gbajugbaja oṣere ni ede oyinbo ati Yoruba lẹẹkọọkan ni, Segun Arinze.

Lẹyin ti wọn bi ọmọ obinrin kan fun ara wọn ni igbeyawo naa tuka.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Arewa Anne Njemanze lo fẹ gbajugbaja oṣere ni ede oyinbo ati Yoruba lẹẹkọọkan ni, Segun Arinze.

Omo obinrin naa ti Anne bi fun Arinze ti di sisi ọmọ ọdun metadinlogun bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood: Kò sí ẹni ti òbí mi kò lè sọ̀rọ̀ sí -Sisi Quadri

Lẹyin eyi ni Anne lọ fẹ Silver Ojieson ṣugbọn wọn kọ ara wọn silẹ latari iwa ipa to n ṣẹlẹ ninu idile wọn.

7. Shan George

Nigba ti oṣere yii wa lọmọ ọdun mẹrindinlogun lọdun 1985 ni wọn ti kọ gbe e niyawo to si bi ọmọ meji fun ọkọ rẹ nigba naa.

Ni igba to di ọdun 1991 ti George pe ọmọ ọdun mọkanlelogun ni wọn kọ ara wọn silẹ.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Anthony Nwaosi naa gbe Shan George ti erin fi jo pa enu won

Awọn kan gbe iroyin boya ahesọ pe Shan tun fẹ ọkọ miran sugbọn igbeyawo ọhun ko yọri si rere.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

Lẹyin eyii ni Shan George fẹ Anthony Nwosisi to jẹ ọkọ rẹ kẹta, sugbọn igbeyawo ọhun ko pẹ to fi tuka bakan naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria Independence Day: Sé ẹ mọ̀ pé ọdún 1956 ló yẹ́ ká ti dòmìnira ṣùgbọ́n....