Nigeria Independence Day: Gbọ́ bí àwọn èèyàn ṣe ń ka ẹ̀jẹ́ Nàìjíríà

Nigeria Independence Day: Gbọ́ bí àwọn èèyàn ṣe ń ka ẹ̀jẹ́ Nàìjíríà

Se iwọ le ka orin ogo ilẹ wa gangan?

Àsía aláwọ̀ ewéko àti funfun, orin ògó ilẹ̀ wa àti ẹ̀jẹ́ orilẹ-ede wà lára àwọn àmì ìdánimọ̀ ọmọ Naijiria.

Lọdun 1960 ninu oṣu kẹwaa ni Naijiria gba ominira kuro lọwọ ijọba amunisin ti ilẹ Gẹẹsi Ǹ jẹ́ o mọ àwọn èèyaǹ wọ̀nyí tó jà fún òmìnira Nàìjíríà?.

Àsía aláwọ̀ ewé àti funfun, orin ògó ilẹ̀ wa àti ẹ̀jẹ́ orilẹ-ede wà lára àwọn àmì ìdánimọ̀ ọmọ Naijiria.

Lẹyin eyi ni a kọ awọn orin ogo ilẹ wa ati ẹ̀jẹ́ fun orilẹ-ede ni eyi ti gbogbo ọmọ Naijiria maa n ka nibi eto akanṣe ati nile iwe.

Ṣaaju ni minista fun ifitonileti, Lai Mohammed fẹ̀sùn kan àwọn ènìyàn Naijiria pé ọ̀pọ̀ wọn ni kò orin ògò àti ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè wa!

Mo ṣe Ileri fun orilẹ-ede mi Naijiria ni ila akọkọ ninu ẹ̀jẹ́ naa to ṣe idanimọ ati imọsilara pe Naijiria yii, ti gbogbo wa ni.

Lati jẹ olododo ati olotitọ eniyan

Ẹni ti o ṣee fi ọkan tan naa tun jẹ awọn amuyẹ to le mu idagbasoke ba Naijiria ti gbogbo wa ba mu ileri yii ṣẹ.

Ẹ jẹ ki gbogbo wa lọ tun orin ogo Naijira ati ẹjẹ yii kọ lede abinibi wa, ki a si fi gbolohun inu rẹ kọ awọn ewe iwoyi ki ọjọ iwaju Naijiria le dun ju bayii lọ.