"A gbúdọ̀ wẹ̀ ọmọ tuntun pẹ̀lú epo pupa, kàìnkàìn ìbílẹ̀ àti ọṣẹ dúdú'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Body Odour: "Olive Oil' tí ílé ìwòsàn kò tó o!"

BBC Yoruba wa pẹlu agbalagba to ni imọ bi wọn ṣe n tọju ọmọ tuntun to ba ṣẹṣẹ dele aye tori wọn gbagbọ pe gbogbo nkan to rọ mọ ọmọ naa lara gbudọ kuro patapata.

Epo pupa, kainkain ibilẹ, ọṣẹ dudu lawọn eroja ti mama yii ka silẹ lati fi tun wẹ ọmọ lẹyin ti wọn ba dele lati ile iwosan.

"Iwẹ ile iwosan yẹn, wọn kan n nu ara fun wọn ni". Mama ni awọn nọọsi gan funrawọn maa n sọ wi pe bi ẹ ba délé, ki ẹ tun ọmọ naa wẹ daadaa gẹgẹ bii abiyamọ.

Wọn a fi epo pa ọmọ naa lara, wọn a wa bẹrẹ si ni fi kainkain ibilẹ gbo o lara titi ti ibọbi to ti wa lara rẹ latinu wa yoo ṣe dá.

"Ni ile iwosan, owu ati ororo nikan ni wọn kan fi n nu wọn lara eyi ko si lee jẹ ki ibọbi to wa lara rẹ da tan".

Mama ṣalaye pe tori ọjọ iwaju ọmọ ni iwẹ naa fi ṣe pataki tori ki o ma baa ni oorun ara "eyi si jẹ itiju gbaa".