Wunmi Toriola, Aisha Lawal, Sotayo àtàwọn ọmọge Yollywood mìí

Awọn ọdọ oṣere Yollywood Image copyright OTHER
Àkọlé àwòrán Wunmi Toriola, Aisha Lawal, Sotayo àtàwọn ọmọge Yollywood mìí

Ọpọ loju teeyan mọ ninu awọn oṣere fiimu Yoruba ti a mọ si Yollywood ṣugbọn ẹni ti yoo yaayi loju ẹnikan yàtọ̀ sẹni ti yoo yaayi loju ẹlomiran.

Gẹgẹ bi awọn to ti di agba ọjẹ ṣe wa laarin wọn ti wọn ṣi dun un wo loju bẹẹ naa lawọn to ti n yọri bọ atawọn to ṣẹṣẹ n yọri naa ni ololufẹ wọn.

Diẹ lara awọn oṣerebinrin tawọn eeyan n kan sara si bi adẹdaa ṣe da wọn ree.

Mercy Aigbe

Image copyright @mercyaigbe

Mercy Aigbe kii ṣe ọmọ Yoruba. A bi oṣere ọmọ Naijiria yii ni ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 1978 lati ilu Benin, olu ilu ipinlẹ Edo.

Oludari ere ni Mercy o si tun jẹ oniṣowo. O ti di ilumọọka oṣere Yoruba to si n sọ ijinlẹ ede Yoruba bi awọn to ni ede gan an.

Ile iwe girama Maryland Comprehensive Secondary School, Ikeja ni ipinlẹ Eko lo lọ.

Bakan naa lo kẹkọọ jade ni ile iwe giga akọṣẹmọṣẹ ti ilu Ibadan nibi to ti kẹkọọ gboye OND ninu imọ eto isuna ko to lọ si fasiti ilu Eko lati lọ kẹkọọ gboye ninu imọ Tiata.

Lẹyin eyi lo dara pọ awọn oṣere tiata lẹkunrẹrẹ lọdun 2006. Oun naa ti ni ile ẹkọ nipa ere ṣiṣe to pe ni "Mercy Aigbe Gentry School of Drama". Mercy Aigbe bu èpè jó àwọn tó ní gómìnà kan ló ra ilé fún-un

Liz Da Silva

Image copyright @lizdasilva

Elizabeth Tekovi Da Silva ni apeja orukọ Liz to jẹ ọmọ Naijiria ṣugbọn ti awọn obi rẹ ara orilẹ-ede Togo bi i ni Lagos Island, ipinlẹ Eko to si dagba ni agbegbe Obalende l'Eko.

Lati igba ti Liz ti wa nile iwe girama lo ti nifẹ si kikopa ninu awọn ere ori itage to si ti n ba wọn kopa nigba naa.

Ọdun 2004 nigba to bẹrẹ pẹlu gbajugbaja oṣere Iyabo Ojo. Ọpọlọpọ ere ibilẹ Yoruba lo ti kopa oun naa si ti ṣe agbejade ere tirẹ gangan.

Hassan, Iyabo Ojo, Ronke Ojo, and Doris Simon, atawọn mii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMama Rainbow: Toyin Adegbola àti Razak Olayiwola ní ìyá rere àti àwòkọ́ṣe gidi ní

Wumi Toriola

Image copyright Wumi Toriola

Oṣere Naijiria to ti n gbori soke ni Wumi Toriola,

Ọmọ ipinlẹ Ogun ni. Imọ ẹkọ nipa ẹda ede (Linguistics) ni Wumi kọ jade lati fasiti ilu Ilorin bẹẹ si lo gboye Diploma ninu imọ ẹkọ Tiata.

Oṣere ni, oniṣẹ ọwọ si ni pẹlu to ti gbajugbaja laarin awọn oṣere Yoruba to bẹrẹ si ni kopa ninu ere lọdun 2013.

O ti kopa ninu ọpọlọpọ ere to le ni aadọta oun naa si ti ṣe agbejade ere tirẹ gangan to to bii mẹta.

Wumi Toriola gbeyawo lọdun 2018 pẹlu ọkọ rẹ to n gbe nilẹ okeere wọn si ti ni ọmọ ọkunrin ninu oṣu kẹwaa, ọdun 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWùnmí Toríọlá: Toyin Abraham kìí se ọ̀gá mi nínú tíátà

Aisha Lawal

Image copyright Aisha Lawal

Laarin awọn ọdọ oṣere Yoruba, Aisha Lawal ti di gbajugbaja pẹlu ara ọtọ to n gba fi itumọ si ipa ti wọn ba fun un lati ko ninu ere.

Yatọ si pe o jẹ oṣere, iwadii fihan pe o tun jẹ alase ati sọrọsọrọ nibi ayẹyẹ.

O kawe ni Adeen International School, Ogbomosho ati ile iwe girama ti awọn akẹkọbinrin, Federal Government College, Ogbomosho.

Aisha kawe gboye ninu imọ ofin ni fasiti Lead City, o si tun kawe gboye onipele kini mii ninu imọ ẹkọ Public Administration.

Aisha Lawal ti kopa ninu ọpọlọpọ ere agbelewo Yoruba ati ede Gẹẹsi.

Bidemi Kosoko

Image copyright bidemi_kosoko

Ile to kun fun awọn oṣere ni Bidemi Kosoko ti ṣẹ wa. Oun funrarẹ naa ni ẹbun yii gẹgẹ bi o ti jẹ ọmọ agba ọjẹ oṣere, Ọmọọba Jide Kosoko.

Bakan naa, ẹni to ku fun un ni iya, oloogbe Henrietta Kosoko naa jẹ oṣere.

Bidemi tun ni ẹgbọn, Sola Kosoko, ti oun naa jẹ oṣere ati ẹgbọn ọkunrin, Tunji Kosoko.

Ọmọ iya kan naa ni Bidemi ati Sola Kosoko, wọn padanu iya wọn lọdun 1993.

Bidemi kawe gboye ninu imọ tiatia lati fasiti ilu Eko. O ti lọkọ Bidemi Kosọkọ di ìyá ìkókó lọdun 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSola Kosoko: ọlá bàbá mi ni mò n jẹ́ nínú iṣẹ́ tíátà

Biola Bayo

Image copyright Biola Bayo

Biola Adebayo naa kii ṣe aimọ fun oloko laarin awọn oṣere Yoruba. Oju rẹ bẹrẹ si ni di gbajugbaja lọdun 2006.

Bo tilẹ jẹ pe lasiko kan oju rẹ ko fi bẹẹ maa jade lori awọn ere agbelewo, bẹẹ naa lo to akoko to gberasọ pada tori naa, Biola Adebayo o ṣee fọwọ rọ sẹyin lagbo awọn awọn oṣere.

Eniola Ajao

Image copyright Eniola Ajao

Ijọba ibilẹ Epe lEko ni wọn ti bi Eniola lọjọ kọkanlelogun, oṣu kinni.

Ibeji ni Eniola jẹ toun ati ikeji rẹ si jẹ abigbẹyin awọn ọmọ mẹfa ti obi wọn bi.

Ile iwe alakọbẹrẹ Saint Michael ni Epe ni Eniola ti bẹrẹ iwe kika. Lẹyin naa ni Eniola lọ si ile iwe girama tawọn ologun ni Epe kan naa.

Fun imọ ẹkọ giga, Eniola kawe gboye ninu imọ iṣiro owo ni ile iwe akọṣẹmọṣẹ Yaba College of Technology ko to lọ si fasiti ilu Eko lati kọ imọ iṣiro owo.

Ere akọkọ ti Eniola ti fojuhan ni Igba Aimo lọdun 2004 lati igba naa lo si ti di oju taye mọ daadaa ninu awọn sinima Yoruba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'

Sotayo Gaga

Image copyright Sotayo Gaga

Sotayo Sobowale lorukọ rẹ ṣugbọn ti apele rẹ n jẹ Sotayo Gaga. Ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni ti wọn bi ni ọjọ kejidinlọgbọn, ọdun 1985.

Iya rẹ jẹ ẹlẹsin musulumi nigba ti baba rẹ jẹ ẹlẹsin Kristẹni.

Fasiti OIlabisi Onabanjo lo ti kawe gboye ninu imọ Public Administration to si tun gboye Diploma ninu imọ ofin lati fasiti ilu Eko.

Inu awọn orin lo ti kọkọ bẹrẹ si ni fojuhan ko to dara pọ mọ sinima agbelewo lede Gẹẹsi, ko to wa re si ti Yoruba to si n ṣe mejeeji sira wọn.

Sotayo ni ile iṣẹ nla kan ti wọn ti n ṣagbejade ere tabi orin nilu Eko.