Omoyele Sowore: Àjo SERAP ké pe ìjọba kó yé fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn dun ọmọ Nàìjíríà mọ́

Omjoyele Sowore Image copyright Instagram/Omoyele Sowore

Ajọ ajafẹto ẹni, SERAP ti fi lẹta kan ranṣẹ si adajọ agba patapata lorilẹ-ede Naijiria, Ibrahim Tanko Muhammad to si rọ adajọ lati ma jẹ ki lo ile ẹjọ lati tẹ oju ẹtọ awọn ọmọ Naijiria mọlẹ.

Lẹta naa ti igbakeji ọga agba SERAP Kolawole Oluwadare buwọ lu, lo jẹ latari awuyewuye to waye lori ẹsun ti ijọba apapọ fi kan Omoyele Sowore to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ Shara Reporters.

Ti ẹ kọ ba gbagbe, ni ọjọ kẹrin oṣu yii ni ile kan da Sowore silẹ. Sugbọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS kọ lati tu silẹ.

SERAP sọ pe ki adajọ agba patapata naa ri pe nigba ti awọn adari ijọba ba kọ eti ikun si aṣẹ ile ẹjọ, ki ẹka iṣeto idajọ naa ri pe wọn ṣe ohun to tọ, bi bẹ kọ, ofin ilẹ yii yoo di ohun yẹpẹrẹ.

Ajọ SERAP bu ẹnu atẹ lu bi ijọba ṣe n tẹ oju ẹtọ awọn ọmọ Naijiria kan mọlẹ, paapaa julọ awọn oniroyin.

Image copyright @RipplesNG

SERAP ni oun gbagbọ pe, ile ẹjọ nikan ṣoṣo lo laṣẹ lati ṣo iru iya to yẹ ki wọn fi jẹ ẹnikẹni to ba ṣẹ sofin, ki sẹ ijọba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOvarian Cancer: Kelliyah Ashley ní ṣe ní ikùn òun le gbandi bíi olóyún