Yoruba Film: Femi Adebayo, Iyabo Ojo ta sí àwọn òṣèré tó ń tọrọ owó láti wo àìsàn

Awọn oṣere Yoruba Image copyright OTHER

Latari bi awọn oṣere tiata ṣe maa n wa iranwọ lasiko ti wọn ba dubulẹ aisan, awọn akẹgbẹ wọn ti bu ẹnu atẹ lu iwa yii ti wn ni ko boju mu ni tiwọn.

Gbajugbaja oṣere Yoruba Femi Adebayo fi ontẹ jan an ni ninu fidio to fi sita tori akẹgbẹ rẹ Iyabo Ojo lo ti kọkọ wu ọrọ yii sita.

Koda o ni o yẹ ki ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni eto adojutofo ati igbaradi fun ilera ara wọn to fi mọ asiko ifẹyinti wọn.

Femi dupẹ lọwọ aarẹ wọn, Mr Latin atawn toku rẹ ti wọn jọ jẹ adari ẹgbẹ o si tubọ pe awọn eniyan ki wọn jade wa ran Gbenga ẹni ti ailera rẹ wu ọrọ yii sita lọwọ.

Ṣaaju Iyabo Ojo tẹnu mọ aidaa to ni o wa ninu ki awọn oṣere maa tọrọ owo lori ẹrọ ayelujara bi aisan ba da wọn dubulẹ.

O dupe lọwọ gbogbo awọn to ti n nawọ iranwọ ni gbogbo igba si awọn oṣere tiata to ba dubulẹ aisan.

Nigba ti o gbọ pe ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ, Gbenga Ajumoke wa lori akete aisan ti wọn si bọ sori ayelujara lati pe gbogbo ọmọ Naijiria fun iranwọ lọrọ yii tun sọ si i lọkan.

O ni bi o tilẹ jẹ pe oun funra rẹ ko tii ki gbogbo ara bọ inu ẹgbẹ naa, o ni ki gbogbo awọn oṣere bẹrẹ si ni fọwọ wẹwọ bayii lati maa ran ara wọn lọwọ.

Iyabo Ojo ni kii ṣe pe oun ko tii dara pọ mọ ẹgbẹ awọn oṣere tabi fi gbogbo ara kopa tori pe wọn ko ki n fi bẹẹ gba awọn ọdọ bii tirẹ laye lati fọhun dipo bẹẹ wọn le ni ẹni bẹẹ ni iwa arifin lọwọ.

Nitorinaa, ko ni aridaju pe otitọ ẹnu oun lee ribi rin jina ninu ẹgbẹ TAMPAN.

O ni ṣugbọn bayii "a ni TAMPAN, bẹẹ si ni awọn ẹgbẹ mii wa fun awọn oṣere Yoruba ti wọn ti le maa jọ dawo lati ran ara wọn lọwọ.

"Tẹlẹ ẹgbẹ ANTP to pa gbogbo oṣere Naijiria patapata pọ tun ni awọn ẹka ẹgbẹ to da lori ẹya iṣẹ tiata ti onikaluku ba yan laayo".

O wa gba awọn ọdẹ ẹgbẹ rẹ atawọn to ti goke agba, atawọn to ṣẹṣẹ n pọn oke lati lọ dara pọ mọ ẹgbẹ yii to ko gbogbo awọn oṣere Yoruba jọ.

Iyabo ni ko si owo to kere ju bi awọn ba ti jọ finukonu lati maa da owo fun iranwo awọn to ba nilo laarin wọn dipo ki wọn maa tọrọ kiri ori ayelujara.

Bi Iyabo ṣe pe awọn akẹgbẹ rẹ lati gbaruku ti ọrọ ti oun fi sita nipasẹ fidio yii naa ni awọn to ti ọrọ rẹ lẹyin naa ti n fesi pe o wi i 're.

Image copyright @iaboojofespris

"Ka maa lọ sori itakun ayelujara ni gbogbo igba lati tọrọ owo, mi o ro pe o dara to fun ẹgbẹ awọn oṣere".

O tẹnu mọ ọ pe pabanbari ohun ti oun fi wu ọrọ yii jade ni pe ki gbogbo awọn oṣere le tu sita lọ dara pọ mọ ẹgbẹ ki wọn si pawọpọ maa ran ara wọn lọwọ bi ẹnikẹni ba ti nilo rẹ lai maa tu ẹgbẹ oṣere laṣiri sita.

Bẹẹ naa ni awọn ọmọ Naijiria ti ko fọwọ si ọrọ to fi sita yii ko dakẹ. Wọn ni ko fi wọn silẹ pe niwọn igba ti awọn oṣere ẹgbẹ wọn ko be ṣe tan lati ran wọn lọwọ, ko buru bi wọn ba tọ araalu lọ.

Image copyright @iyaboojofespris
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlumo Rock: Òrìṣà Igùn lọba ọ̀pọ̀ òrìṣà tó wà lábẹ́ Olúmọ tó ń dáhùn àdúrà