Family Matters: Ibi tó kọ sí àwọn òbìnrin, ọ̀tọ̀

Opo to n ṣọfọ Image copyright Getty Images

Ọpọlọpọ sọ pe lootọ, opo obinrin lẹtọ lati fẹ ọkọ mii ṣugbọn ki o fẹ ẹ sinu ile ti oun ati ọkọ rẹ n gbe laaye rẹ ni ko boju mu.

Ọkunrin to jẹ alejo lori eto yari kanlẹ pe ko boju mu ki ọkunrin mọ pe ile ti ọkọ ti ẹni ti o fẹ fẹ kọ silẹ ni o fẹ lọ maa gbe ko si tun tẹsiwaju.

"Ọkùnrin tó bá kó lọ ilé opó tó ṣẹ́ṣẹ́ fẹ́ ẹ lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ̀ kò ní ìtìjú rárá".

Ni ti odinnrin to wa lori eto, "awọn agba ni bi a ba n ṣe ọrẹ yẹ ka maa faye ija silẹ". O ni ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ owo ni obinrin mii, owo ti obinrin mii ni ju ti ọkọ lọ.

O ṣalaye pe awọn obinrin mii wa to jẹ pe wọn jọ jiṣẹ jiya pẹlu ọkọ ko to ku ni to wa di pe ọkọ ku tan wọn a ni ko ni le fẹ ọkọ mii sile kan naa.

"Ki lobinrin ṣe ti wọn ma n fẹ fi wọn ṣeru?"

Koda awọn to da si i loju opo Facebook bbcnewsyoruba naa n sọ ti wọn loniruuru ọna.

Akejo ọkunrin ba fesi pe "ta lo tilẹ mọ pe boya obinrin naa ati ọkunrin yẹn ni wọn jọ gbimọ pọ pa ọkọ yẹn".

Obinrin fi owe kun ọrọ rẹ pe "ibi ko ju ibi, baa ṣe bi ẹru la bi ọmọ" eyi to tumọ rẹ wi pe bi opo ọkunrin ba lee fẹ iyawo mii sinu ile ti oun ati ọkọ rẹ n gbe, ki lo de ti obinrin ko lee ṣe bakan naa.

O ni bo ba ṣe iyawo lo ku, laarin ọsẹ meji si mẹta, ọkunrin mii ti gbọn ara nu wọn a ti mu aṣọ sọrun wọn a ti maa jade ṣugbọn to ba ya awọn Yoruba a ni obinrin ko le dan iru aṣa bẹẹ wo labẹ aṣa yii.

"Ṣe iya lo wa tọ si obinrin yẹn to ti fi ọjọ aarọ rẹ pawọpọ kọ ile pẹlu ọkọ aarọ. To ba wa jẹ pe ile yẹn naa ni o lagbara lati gbe pẹlu ọkọ to ṣẹṣẹ fẹ, ki lo de ti ko ni le gbe e?"

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfrica Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́

Ṣe igberaga wa ni fun awọn ọkunrin ni, tabi ofin ni abi aṣa?

Alejo ọkunrin lori eto ka a si pe kii ṣe ifẹ gidi ni yoo mu ki ọkunrin kan ko lọ sile ọkunrin mii to tilẹ tun ti ku lọdọ ẹni to fẹ fẹ.

O ni ewu to wa ninu rẹ ni oun pataki ti oun n wo.