Ṣé ẹ̀yin mọ orúkọ tí Yorùbá ń pé 'Necklace'?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kini Yorùbá ń pe Necklace?

Ṣe eyin naa mọ orukọ ẹ̀ṣọ́ ara aya yín?

Oriṣiriṣi ẹ̀ṣọ́ ara ni awọn obinrin ati ọkunrin iran Yoruba maa fi n dárà si agọ ara wọn.

Ọpọ obinrin maa n lo ẹṣọ ara lati fi ṣafikun ẹwa wọn, fun idanimọ bii ilẹkẹ ayaba, ọmọ Oba ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ki ede Yoruba ma baa parun ni BBC Yoruba ṣe jade lọ beere lọwọ awọn ọkunrin, ohun ti Yoruba n pe " Necklace'.

Ẹ̀gbà ọrùn ni Yoruba n pe Necklace!

Ko si ọrọ naa ni ede oyinbo tabi ni ede kankan ti Yoruba ko ni ọrọ ti wọn fun un nitori pe ki agbado to daye, kini kan ni adiyẹ n jẹ.

Related Topics