Àwọn obìnrin orílẹ̀-èdè Iran yóò wo bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá fún ìgbà àkọ́kọ́ lóní

Awọn obinrin Iran Image copyright @90min_Football
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ awọn obinrin Iran lo ti gbaradi loni lati foju ganni idije bọọlu fun igba akọkọ

Ọpọlọpọ orilẹ-ede agbaye ni ko fun awọn obinrin lanfani lati ṣe awọn ohun kan ti awọn okunrin lee ṣe.

Sugbọn lati ọdun diẹ sẹyin ni ayipada ti n de ba awọn ofin naa, ti awọn obinrin si ti n ni oreọfe lati dawọle awọn ohun naa bi wiwa ọkọ, kikopa ninu idibo, eti bẹbẹ lọ.

Eyi lo mu BBC wo awọn orilẹ-ede to fofin de awọn obinrin lori awọn ohun kan tẹlẹ, sugbọn ti wọn ti gba awọn obinrin laaye lati ṣe awọn ohun naa bayii.

1. Iran

Oni yii ni awọn obirin ni orilẹ-ede Iran yoo lanfani lati wo idije bọọlu alafẹsẹgba lori papa fun igba akọkọ lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Idije naa ti yoo waye laarin ikọ orilẹ-ede Iran ati Cambodia, ni yoo waye ni papa iṣere Azadi, to wa ni Tehran, fun igbaradi idije ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2022.

Ni bayii ti awọn obinrin Iran ti lanfani lati wo idije ori papa fun igba akọkọ, ọpọlọpọ awọn obinrin orilẹ-ede naa lo ti gbaradi loni lati foju gaanni idije ọhun.

2. Saudi Arabia

Lati ọpoọlọpọ ọdun sẹyin ni obinrin Saudi ko ti lanfani lati wa ọkọ, sugbọn lati ọdun 2017 n i nnkan ti bẹrẹ si n yipada.

Ni bayii, awọn obinrin ni Saudi ti n wa ọkọ funrawọn, wọn si lee jade lọ si ibikibi lai si pe ọkọ wọn tele wọn lẹyin.

Bẹẹ naa ni obinrin tun lee kopa ninu idibo ati lati gbe apoti idibo, eyi ti ko ri bẹ tẹlẹri.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKini Yoru[bá ń pe Necklace?

Ko tan sibẹ, awọn obinrin ni Saudi ti lẹtọ labẹ ofin lati lọ wo sinima nile sinima, wọn tun ti le da okowo tiwọn silẹ lai lọwọ ọkọ wọn ninu.

Awọn obinrin Saudi lee ṣere idaraya ita gbangba bayi, wọn si tun ti lẹtọ labẹ ofin lati darapọ mọ ẹgbẹ ologun, eyi ti ko ribẹ tẹlẹri.

3. Rwanda

Tẹlẹri, orilẹ-ede Rwanda ko ka awọn obinrin si.

Sugbọn ni ọdun 2003 ni orilẹ-ede ọhun gba awọn obinrin laye lati ni ida ọgbọn ijoko ni ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede naa.

Ni bayii, nnkan ti ṣẹnu ire fun awọn obinrin, nitori awọn lo ni aga ida ọgọta ni ile aṣofin kekere, ti wọn si ni aga to jẹ ida mejidinlogoji nile aṣofin agba orilẹ-ede ọhun.

4. Pakistan

Iku ni ere ẹnikẹni to ba ṣe ayipada lati akọ tabi abo si akọ lorilẹ-ede Pakistan tẹléri, sugbọn orilẹ-ede ọhun ti fun awọn irufẹ awọn eeyan bẹẹ lẹtọ labẹ ofin lọdun 2009.

Ni oṣu kẹrin ọdun yii ni ijọba Pakistan gba awọn to ba ti ṣe iyipada lati akọ si abo tabi abo si akọ lati le darapọ mọ ajọ ọlọpaa ilẹ ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfrica Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́

5. Iceland

Lati ọdun 1961 ni orilẹ-ede Iceland ti n san owo oṣu to kere fun awọn obinrin, ti ko si ribẹ fun awọn okunrin.

Sugbọn ni ọdun 2018 ni ijọba orilẹ-ede ọhun yi ofin pada to si kan nipa fun awọn ileeṣẹ lati ma san iye owo kan fun takọtabo.

Ijọba ọhun ni, bẹrẹ lati ọdun 2022, ileeṣẹ ti ko ba tẹle ofin naa yoo fojuba ile ẹjọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKini Yoru[bá ń pe Necklace?