EFCC ti ri mílíọ̀nù 65.5 owó naira ni ọọfiisi àjọ INEC ni Zamfara

owo
Àkọlé àwòrán,

Aduru owo yii lo wa nipamọ ni iyara kan!

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC ti ri N65, 548, 000: 00 ninu ọọfiisi ajọ eleto idibo INEC nipinlẹ Zamfara.

Lọjọ ru ni EFCC kede pe awọn ri owo naa ninu ibi ifowopamọ si ninu ọọfiisi ọga agba to n ṣamojuto inawo ajọ INEC ni Zamfara ni apa ariwa Naijiria.

Wọn ni ninu bọndulu owo lọna mọkanlelọgọrin ni odiwọn ẹgbẹrun kan naira ati bọndulu mẹtadinlọgọrun ni ẹẹdẹgbẹta naira ati iye mẹrindinlọgọrun un to lẹe ni wọn ri nibẹ.

Ajọ EFCC ni wọn lọ ṣe iwadii owo naa ni kete ti wọn ri iwe ẹsun gba lati ọwọ oṣiṣẹ fifihẹ kan ti INEC lo lasiko idibo to kọja.

Oṣiṣẹ yii wa lara awọn to ṣiṣẹ lasiko idibo gomina ati ti aarẹ tọdun 2019.

Àkọlé àwòrán,

Ha! ni onikaluku lanu silẹ pe kini owo yii wa fun?

Oṣiṣẹ fidihẹ to ba INEC ṣiṣẹ to kọwe ẹsun yii ṣalaye pe ajọ eleto idibo Zamfara kọ lati san owo ọya awọn oṣiṣẹ wọnyii.

O ni ẹgbẹrun mẹfa ti awọn jọ ṣadehun rẹ ni ajọ INEC kọ lati san fawọn oṣiṣẹ ti wọn lo lasiko yii.

Ajọ EFCC ni ara fu awọn pe owo ti wọn ri yii ṣeeṣe ko jẹ ninu owo tijọba ko silẹ lati na lasiko idibo to kọja.

Wọn ni ijọba la owo kalẹ lati na fi gba atibaba, gba aga, tabili atawọn ohun eelo abẹle miran lasiko idibo to kọja.

Àkọlé fídíò,

Suicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni

Ajọ eleto Idibo INEC ko tii sọrọ lori iṣẹlẹ yii paapaa ohun ti owo yii wa fun ni pato.

Àkọlé fídíò,

Kini Yoru[bá ń pe Necklace?