Senate: Ṣé kí Nàìjíríà dín iye àwọn Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú wọn kù ni tàbi ka kuku pa ipò náà rẹ́?

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Owo ti a ba ri yii a ran wa lọwọ lati ṣe nkan fawọn ara ilu

Ṣé kí Nàìjíríà dín iye àwọn Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú wọn kù ni tabi ki a kuku ma dibo yan wọn mọ ni?

Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ni asiko ti to ka fopin si ipo awọn sẹnetọ ni Naijiria lasiko yii ki orilẹ-ede yii le ri owo na.

O ni awọn senetọ ti n na owo to pọju ni eyi ti ijọba yi le fi owo naa ṣe nkan miran fawọn ara ilu.

O gba ijọba nimọran lati ṣamulo abọ iwadii awọn igbimọ Orosaye Stephen.

Abọ iwadii Orosaye ni pe ki wọn da awọn ileeṣe ijọba apapọ ti ṣe wọn jọra wọn di ọkan ṣoṣo ki wọn le gbooro sii.

Fayẹmi gba imoran yii lasiko ti o n sọrọ nibi apero lori eto ọrọ aje Naijiria ẹlẹẹkẹdọgbọn iru rẹ ti akori rẹ jẹ: Naijiria ni 2050: ki lo ku ni ṣiṣẹ yatọ?

Kini Okorocha sọ lori awọn sẹnetọ?

Ṣaaaju ni gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, Rochas Okorocha ti kọkọ ni ki wọn din odiwọn iye awọn aṣojusofin ku nile ijọba ni Abuja.

Rochas ni senetọ to n ṣoju iwọ oorun ipinlẹ Imo bayii nile igbimọ ijokoo kẹsan an.

O ni iye owo ti sẹnetọ kọọkan n na ti pọju loju toun ati pe o yẹ kijọba din wọn ku si ẹyọ kan lati ipinlẹ kọọkan dipo mẹta yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionClaudiah: ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi fínra fún ọpọlọpọ ọdún

Lọwọlọwọ ni Naijiria, awọn aṣoju jẹ mọkandinlaadọfa nile igbimọ aṣofin agba nilu Abuja lati ipinlẹ mẹrindinlogoji ati FCT.

Nigba ti awọn aṣojuṣofin jẹ ọtalelọọdunrun nile igbimọ aṣojuṣofin kekere ni Abuja.

Ninu aba eto iṣuna tuntun tọdun 2020 ti ijọba apapọ gbe wa siwaju ile laipẹ yii lo ṣafihan pe biliọnu mẹẹdọgbọn le ni ọgọrun un ni awọn aṣoju wọnyii yoo na tan. Okorocha

Gomina Fayemi ni oun ko ro pe ọrọ Naijiria nilo aduro ero yii lati maa na owo ti wọn n na tan loṣooṣu ki a to lè yanju iṣorọ Naijiria.

O ni awọn aṣojuṣofin la nilo lati ṣe agbẹkalẹ awọn ofin to yẹ ni Naijiria kii ṣe awon sẹnetọ rara.

Fayẹmi fi ipinlẹ Ekiti rẹ ṣe apẹrẹ pe kini sẹnetọ mẹta n ṣe lati Ekiti kekere yẹn ki ato sọ awọn ipinlẹ ti ko tun tobi to Ekiti.