Ambode: Kí ló ń fa awuyewuye láàrín ilé aṣòfin Èkó àti Gómìnà tẹ́lẹ Ambode?

Ambode Image copyright Google
Àkọlé àwòrán A kó dúkòkò mọ́ Ambode, isẹ́ wa là ń ṣe - Ilé Aṣòfin Eko

Ṣe ni royin n tan ka pe ile aṣofin ipinlẹ Eko ti tutọ soke pe awọn yoo fi ọlọpaa mu Gomina ana ipinlẹ naa, Akinwumi Ambode lori ẹsun ṣiṣe owo ọba kumọkumọ.

Lọjọbọ ni iroyin gbode pe ile fi ọrọ yii lelẹ nigba ti wọn n ṣe agbekalẹ iwaadi igbimọ to n wadi ọrọ nipa bi Gomina ana ti ṣe na owo ọkọ akero lasiko to wa lori ijọba.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Cable ti ṣe sọ, alaga igbimọ iwadii naa, aṣoju Fatai Mojeed lawọn rii wi pe Gomina Ambode ko tẹle ilana to yẹ ki wọn to ra awọn ọkọ akero 820.

Ṣaaju asiko yIi ni ile ti pinu lati mọ bi Ambode ṣe na ₦45b tó fi ra BRT.

Loju opo Twitter ile aṣofin wọn fi ọrọ to jọ pe awọn aṣofin jiroro lori ọrọ yi.

Yatọ si Gomina Ambode, ile sọ pe awọn yoo f'ọlọpaa mu awọn kọmisana mẹrin to ṣiṣẹ lasiko Ambode tawọn naa kọ lati yọju si igbimọ iwadii ile.

Awọn Komisana naa ni Kazeem Adeniji (eto idajọ), Olusegun Banjo (isuna), Akinyemi Ashade (inawo) and Wale Oluwo (oun iṣagbara ati oun alumọni).

A gbiyanju lati ba aṣofin Gbolahan Yishau to jẹ ọkan lara awọn to sọrọ nipa iṣẹlẹ yi lasiko ijiroro ile ṣugbọn oju opo ibanisọrọ ko lọ gere.

A ko tii ribi fidi ọrọ mulẹ lati ọdọ Gomina ana boya ile ti fiwe pe e lati wa wi tẹnu rẹ.

Ki Ambode to kuro lori oye gẹgẹ bii Gomina ni oun ati awọn ile aṣofin ti n jijọ wọ ṣokoto kan naa paapa lori bi o ṣe n na awọn owo kan ti ile ni awọn ko fun un ni iyọnda lati na.