Shakil Afridi: Dókítà tó ran àjọ CIA lọ́wọ́ láti rí Bin Laden mú

Shakil Afridi Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Afridi ni oun kjo jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn kan oun

Dokita ọmọ orilẹ-ede Pakistan to ṣe iranlọwọ fun ajọ ọmọ ogun ilẹ Amẹrika lati le mu gbajugbaja ajijagbara nni, Osama Bin Laden ti pe ẹjọ kotẹmilọrun lodi si bi wọn ṣe fi sinu ẹwọn.

Ẹjọ kotẹmilọrun ti dokita Shakil Afridi pe jẹ igba akọkọ ti ile ẹjọ yoo gbọ ẹjọ rẹ, ṣugbọn adajọ ti sun ẹjọ naa si ọjọ kejilelogun oṣu yii.

Ipa ti Afridi ko lati jẹ ki wọn ri Osama Bin Laden mu, ni ijọba orilẹede rẹ ti juwe gẹgẹ bi ohun itiju nla fun wọn.

Afridi sọ pe, idajọ ti wọn ṣe fun oun ko tọna, latari bi ijọba ko ṣe pe e lẹjọ kan pato fun ipa to ko ninu iranlọwọ to ṣe pẹlu ilẹ Amẹrika lati mu Bin Ladin.

Awuyewuye to waye lẹyin ti wọn sọ Afridi sẹwọn pọ to bẹẹ gẹ, ti orilẹede Amẹrika fi dẹkun iranlọwọ rẹ si orilẹede Pakistan, leyi to to miliọnu mẹtalelọgbọn dọla.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ni ṣe ni Bin Laden n yọri bọrọ ki ọwọ to tẹ lọdun 2011

Ṣaaju ni aarẹ orilẹ-ede Amẹrika, Donal Trump ṣeleri ninu ipolongo rẹ sipo aarẹ pe oun yoo gba Afridi silẹ laarin "iṣẹju meji" ti wọn ba lee dibo fun oun - sugbọn ko tii mu ileri naa ṣẹ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan Amẹrika ri dokita ọhun bii akinkanju ọkunrin, awọn ara ilu rẹ ni Pakistan n wo o bi ọdalẹ to dojuti orilẹede wọn.

Tani Shakil Afridi?

Dokita Shakil Afridi jẹ ọkan gboogi lara awọn oniṣegun oyinbo to wa ni agbegbe Khyber.

O jẹ olori awọn onimọ ilera ni agbegbe naa, o si tun n ṣe akoso awọn eto abẹrẹ ajẹsara kan ti ilẹ Amẹrika n ṣagbatẹru rẹ ni agbegbe ọhun.

Afridi ṣagbatẹru abẹrẹ ajẹsara fun aisan jẹdọjẹdọ ni ilu Abbottabad, ni ibi ti Bin Laden n gbe, ti ajọ ologun si wa, sugbọn ti wọn ko mọ.

Ero awọn ọtẹlẹmuyẹ Amẹrika ni lati ṣe ayẹwo ẹjẹ awọn ọmọ to wa ni Abbottabad yii, lati fi mọ boya, awọn ọmọ naa jẹ ibatan Bin Laden.

Iroyin ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ Afridi gba ẹjẹ ọmọ kan, ṣugbọn wọn ko fi idi rẹ mulẹ boya ẹjẹ naa ni wọn fi ṣawari Bin Laden.

Ọjọ kẹtalelogun oṣu karun un ọdun 2011, lẹyin ogun ọjọ ti ileeṣẹ ologun Amẹrika pa Bin Laden ni ijọba Pakistan fi sikun ọba mu Afridi, ni igba to wa ni ọmọ aadọta ọdun din diẹ.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ile ti Osama Bin laden gbe ni Pakistan lọdun 2012 ki wọn to wo palẹ

Dokita Afridi jẹ ọmọ atapata dide. O kawe jade ni ileewe ẹkọṣẹ iṣegun Khyber, ni ọdun 1960.

Inu ibẹrubojo ni awọn ẹbi dokita yii wa lati igba ti wọn ti fi panpẹ ọba mu u, latari ibẹru awọn ẹgbẹgun agbesumọmi.

Iyawo Afridi jẹ ọkan gboogi lara awọn oṣiṣẹ ile iwe kan ni Abbottabad ko to lọ sa pamọ.

Tokọtaya naa bi ọmọ mẹta, obinrin kan ati okunrin meji, ti awọn ọmọ naa si ti di gende bayii.

Ni oṣu kini ọdun 2012, ijọba ilẹ Amẹrika sọ ni kedere pe Afridi ṣe iranlọwọ fun ajọ ọtẹlẹmuyẹ oun.

Iwaadi kan ti orilẹede Pakistan ṣe fihan pe, Afridi ko mọ ẹni gan pato ti ilẹ Amẹrika n wa ni igba ti wọn bẹ ẹ lọwẹ.

Image copyright Reuters

Ẹsun wo lo ṣo Afridi dero ẹwọn?

Lakọkọ, wọn fi ẹsun igbimọditẹ kan Afridi, sugbọn oṣu karun un ọdun 2012 ni wọn sọ ọ si ẹwọn, lẹyin ti wọn ni o jẹbi ẹsun ṣiṣe iranlọwọ owo fun ẹgbẹ Laskar-e-Islam, eyi ti ijọba ti fi ofin de ṣaaju.

Ijọba ran Afridi lẹwọn ọdun mẹtalelọgbọn fun ibaṣepọ rẹ pẹlu ẹgbẹ naa, ṣugbọn lẹyin o rẹyin, wọn din ẹwọn naa ku si ọdun mẹtalelogun.

Ẹwẹ, awọn mọlẹbi rẹ ni ọrọ ko ri bẹẹ, awọn agbẹjọro rẹ si sọ wi pe owo to fun awọn agbesumọmi ọhun jẹ ẹgbẹrun meje dollar o din diẹ, owo to san fun wọn lẹyin ti wọn ji gbe.

O sọ fun iwe iroyin Fox lọdun 2012 pe, ajọ ọtẹlẹmuyẹ Pakistan n fi iya jẹ oun lọna ti ko tọ ninu ẹwọn ti oun wa.

Kini idi ti wọn ko ṣe fi ẹsun kan Afridi lori iranlọwọ rẹ fun ilẹ Amẹrika?

Ko si ẹni to le sọ, ṣugbọn ọrọ Bin Laden ọhun jẹ itiju nla fun orilẹede Pakistan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni

Adari awọn to n gbogun ti iṣerubalu lorilẹede Amẹrika nigba naa, John Brennan ni, o ṣoro lati gbagbọ pe Bin Laden n gbe ni Pakistan lasiko naa, ti ijọba orilẹede ko si mọ, ṣugbọn ijọba ilẹ ọhun ni ọrọ ko ri bẹẹ.

Kini idi ti ọrọ Afridi fi dele ẹjọ lasiko yii?

Awọn ile ẹjọ to wa ni igba ti wọn sẹ idajọ Afridi wa labẹ awọn agba ilu, ti wọn ki tẹle ilana ofin lẹkunrẹrẹ, eyi to fun awọn alakoso ile ẹjọ naa lanfani lati ṣe ẹjọ rẹ nikọkọ.

Lẹyin ti wọn ti gbe e kuro ni ẹwọn to wa ni Peshawar lọ si Punjab, awọn kan n sọ pe o ṣeeṣe ki wọn fi silẹ.

Iroyin kan ni ki wọn fi rọpo Aafia Siddiqui, to jẹ ọmọ ẹgbẹgun al-Qaeda to n ṣẹwọn lọwọ lorilẹede Amẹrika.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKini Yoru[bá ń pe Necklace?