Justice for Ochanya: ìjọba Benue á bẹ̀rẹ̀ ẹjọ́ ẹni tó fipá bá ọmọ ọdún 13 lò lẹ́yìn ikú rẹ̀

Awọn to n ṣe iwọde leyin iku Ogbanje Image copyright @Austynzogs
Àkọlé àwòrán Awọn ajafẹtọ ẹni ni ipinlẹ Benue ni odun mọ wọn ninu bi ijọba ipinlẹ ọhun ṣe mu ọrọ naa logiri lasiko yii

Afurasi ti wọn fi ẹsun kan pe o fi ipa ba ọmọ ọdun mẹtala lo foju ba ile ẹjọ loṣu to n bọ, lẹyin ọdun kan ti ọmọ naa di ologbe.

Igbẹjọ Andre Ogbuja, ti wọn ni o fi ipa ba Ochanya Ogbanje to jẹ ọmọ ọdun mẹtala lo pọ ni ipinlẹ Benue yoo bẹrẹ lati ọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla, ọdun yii.

Ijọba ipinlẹ Benue ni aarin gbungbun Naijiria ni o n gbe Andre lọ ile ẹjọ giga lori ẹsun mẹrin to rọmọ ifipabanilopọ ati ipaniyan.

Iṣẹ bii ọmọ ọdọ ni Ochanya n ṣe ni ile Ogbuja ko le ni anfani lati lọ ile iwe, bi o tilẹ jẹ pe wọn ni ẹbi ni oun ati iyawo olukọ ile iwe giga yii.

Lẹyin naa lo dubulẹ aisan, ki o to di ologbe loṣu kẹwaa ọdun 2018 ko to di pe o fi eṣun kan Andre ati ọmọ rẹ okunrin pe, wọn n fi ipa ba oun lopọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKemi Lala: mo ń gbìyànjú láti mú inú òbí mi dùn

Iku rẹ dun awọn ọmọ Naijiria to bẹ gẹẹ ti wọn fi ṣe iwọde ita gbangba ki ijọba le fi awọn to lọwọ ninu iku rẹ jofin.

Lẹyin ọdun kan ti ọmọdebinrin naa ti di ologbe, ni ijọba ipinlẹ Benue n mu ọrọ iku ọmọ ọhun lọkunkundun.

Afurasi ọhun to jẹ olukọ agba ni ile ẹkọ gbogboniṣe ipinlẹ Benue ni oun ko jẹbi ẹsun naa.

Agbẹjọro fun ijọba, PM Ukande rọ ile ẹjọ lati fi okunrin naa si atimọle, titi di igba ẹjọ naa yoo bẹrẹ loṣu to n bọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPalmwine Tapping: Ọ̀dọ́mọdé àdẹ́mu ní ìṣẹ́ náà kò wú òun lórí

Sugbọn agbẹjọro fun afurasi naa, Abel Onoga ni, oun ko lodi si ipẹjọ naa, sugbọn ki agbẹjọro fun ijọba mu ẹlẹri to dantọ wa si ile ẹjọ.

Awọn ajafẹtọ ẹni ni ipinlẹ Benue ni odun mọ wọn ninu bi ijọba ipinlẹ ọhun ṣe mu ọrọ naa logidi lasiko yii, nitori ọrọ ifipa banilopọ ti n gba ẹbọ lọwọ awọn eniyan ipinlẹ Benue.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKini Yoru[bá ń pe Necklace?