Islamic State: Ilẹ̀ Amẹrika ń kó àwọn ọmọ ogun IS tó burù kúrò ní Syria- Trump

Awọn ọmọ ẹgbẹgun IS ti ọwọ awọn ogun Kurd tẹ Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Aarẹ Trump ni awọn afurasi ọhun ni wọn ma n bẹ ori eeyan ni Syria

Meji lara awọn ọmọ ẹgbẹ ogun Islamic State, IS, ni wọn ti gbe kuro ni Syria lọ si agbegbe kan ti ijọba ilẹ Amẹrika n ṣakoso rẹ bayii.

Awọn eeyan naa, El Shafee Elsheikh ati Alexanda Kotey, ni wọn fi ẹsun kan pe wọn darapọ mọ ẹgbẹ egbesumọmi IS, ti wọn si n ṣeku pa awọn eeyan ni Syria.

Iroyin lati orilẹ-ede Amẹrika ni, awọn okunrin meji ọhun ni wọn jẹ ọmọ ogun ilẹ Amẹrika.

Ninu ọrọ to fi soju opo Twitter rẹ, aarẹ orilẹ-ede Amẹrika, Donald Trump ni, iṣẹlẹ naa jẹ eyi to buru jọjọ.

Gẹgẹ bi iroyin ti il iṣẹ New York Times ati Washignton Post gbe jade, awọn meji yii ni wọn le kuro ni ẹwọn ti awọn ọmọ ogun Kurd n ṣakoso rẹ ni Ariwa orilẹ-ede Syria.

Iroyin naa ni wọn fi lede lẹyin ti ijọba Amẹrika ko awọn ọmọ ogun rẹ kuro ni agbegbe ọhun lọsẹ yii.

Aarẹ Trump sọ fun awọn oniroyin lọjọru pe, ilẹ Amẹrika ti n ko awọn ọmọ ogun IS to buru julọ kuro ni Syria.

O ni wọn n ṣe eyi nitori ibẹru pe wọn le bọ kuro ninu ẹwọn bi awọn ọmọ ogun ilẹ Turkey ṣe n ṣakọlu si agbegbe ọhun.

Lara awọn ọmọ ẹgbẹgun IS miran ti wọn mọ si "The Beatles" ni Mohammed Emwazi, ti apẹle rẹ n jẹ Jihadi John, ti wọn pa lọdun 2015 ati Aine Davis, to n faṣo penpe roko ọba lọwọ ni orilẹ-ede Turkey.

Awọn eeyan naa lo darapọ mọ awọn agbesumọmi ọhun ni ilẹ Gẹẹsi ki wọn to rinrin ajo lọ si Syria, sugbọn ijọba orilẹ-ede United Kingdom ti kọ̀ wọn gẹgẹ bi ọmọ orilẹ-ede rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKemi Lala: mo ń gbìyànjú láti mú inú òbí mi dùn