Rape: Títẹ àwọn afipábánilopọ̀ lọdàá kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ sí ìwà ìfipábánilopọ̀ - Ọmọ Nàìjíríà

Awọn to npolongo lodi si ibalopọ Image copyright Getty Images

Awọn ọmọ Naijiria kan ti ni titẹ okunrin lọdaa ki ṣe ọna abayọ si iwa ifipabanilopọ.

Ọrọ yii ni awọn eeyan kan sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, lẹyin ti ijọba ipinlẹ Ekiti daba lati máa tẹ awọn okunrin to ba fi ipa ba obinrin lajọṣepọ lọdaa.

Aṣoju ile isẹ Women Consortium of Nigeria, Morenike Omaiboje sọ fun BBC pe, ipa ti iṣẹlẹ ifipabanilopọ n ko ninu aye awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si pọ ju ki ijọba da awọn afurasi ẹsun naa lọdaa lọ.

O ni o yẹ ki wọn ṣe ju bẹẹ lọ fun awọn oniṣẹ ibi oloju komu-ko-lọ wọnyii.

O ni, titẹ awọn to ba fipa ba obinrin laṣepọ lọdaa le din iru iwa bẹẹ ku, sugbọn ko le fi opin si iwa ọhun.

Morenike ṣalaye pe, bo tilẹ jẹ pe ijọba n fi iya jẹ awọn ọdaran lori ẹsun miran, eyi ko da iru iwa bẹ duro.

O wa rọ ijọba lati ti gbe igbeṣe to dantọ lọna lati fopin si iwa ifipabanilopọ lorilẹ-ede yii.

Bẹẹ naa lo rọ awọn obi lati kọ awọn ọmọ wọn lati kekere, lati ma ṣora ṣe lẹgbẹ awọn okunrin ti wọn ko ba mọ daadaa.

Bawo ni wọn ṣe le tẹ okunrin lọdaa?

Dokita Thomas-Wilson Ikubeseto jẹ oniṣegun eto ilera ni, titẹ okunrin lọdaa jẹ ọna ti wọn fi n yọ koropọn okunrin kuro ni ipo to wa.

Ikubese ni titẹ okunrin lọdaa ko da ibalopọ duro.

O sọ pe okunrin ti wọn ba tẹ lọdaa si le ta kebe bi okunrin, sugbọn iru okunrin bẹ ko ni le fun obinrin loyun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKemi Lala: mo ń gbìyànjú láti mú inú òbí mi dùn

Kini awọn eeyan n wi?

Ọgbẹni Odewale Omokehinde sọ fun BBC pe, o dara ki ijọba maa tẹ awọn okunrin to ba fi ipa ba obinrin lajọsẹpọ lọdaa.

O ṣalaye pe oun gbagbọ pe iru ijiya bẹẹ le dẹkun iwa ifipabanilopọ lorilẹ-ede yii.

Sugbọn ọgbẹni Uwem Okon ni tire tako ọrọ yii, o ni oun ko fara mọ ki ijọba tẹ awọn afurasi lọdaa nitori ẹsun ifipabanilopọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni

Uwem sọ pe oriṣiriṣi idi ni awọn eeyan ṣe le fi ipa banilopọ, bi arun ọpọlọ ati awọn awọn idi miran.

O sọ siwaju si pe, ti ijọba ba ṣe bẹ, iru ijiya naa yoo sọ iṣoro ọhun di abala meji ni.

Ọgbẹni Uwem kin ọrọ rẹ lẹyin pe, bi idajọ iku ko ṣe dẹkun iwa ipaniyan, bẹ naa ni titẹ awọn afipabanilopọ lọdaa ko le dẹkun iwa ifipabanilopọ.

Jessica Nabongo ni obìnrin àkọkọ nílẹ Adúláwọ tó rin gbogbo àgbáyé.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn òfegè ni pé Buhari fẹ fẹ́ Sadiya, síbẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣètò ìyàwò náà lórí ayélujára

Ọpẹ́ o! Àwọn ologun dóòlà akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà lọ́wọ́ àwọn ajínigbé ní Kaduna

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionClaudiah: ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi fínra fún ọpọlọpọ ọdún