Seyi Awolowo: Torí mo fẹ́ j'ólórúkọ ni mo ṣe lọ fún ètò Ẹlẹ́gbọ́n Àgbà

Seyi Awolowo Image copyright Yetunde Olugbenga

Seyi Awolowo ni oun fẹ ni orukọ toun ni yatọ si orukọ Baba Baba oun ti gbogbo agbaye mọ.

Seyi Awolowo dupẹ lọ́wọ́ lórí akanṣe eto BBC Yorùbá dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ fún gbogbo ibo ti wọn di fun un nile Ẹlẹgbọn agba eyi ti gbogbo eeyan mọ si Big Brother Nigeria.

Kí ló sún Seyi dé ilé ẹlẹ́gbọ́n àgbà?

"Gbogbo eeyan lo mọ mi ni Awolowo, Seyi, ọmọ Awolowo ṣugbọn mo fẹ ni orukọ temi to bẹẹ to jẹ pe ti mo ba ṣe nkan ni'ta, wọn a sọ pe Seyi lo ṣe e, kii ṣe Awolowo".

Eyi ni esi Seyi gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe fẹ mọ idi pato to fi lọ fun eto yii tori wọn mọ pe olorukọ ati onile ọlọna ni. Seyi ni "mo fẹ ko jẹ wi pe bi mo ba ṣe ohunkohun emi, Seyi ni mo ṣe e kii ṣe Awolowo".

Araale: Ọmọ ọdun melo gan ni Seyi Awolowo, ati pe ṣe Dokita ni?

Seyi: Ọmọ ọgbọn ọdun ni Seyi. Mi o kii n ṣe Dokita rara o, ibi ti mo ti ṣiṣẹ ri ni wọn ti fun mi lorukọ yẹn o 'Doc' lati igba naa lawọn eeyan ti n pe mi bẹẹ.

Mo kawe o ṣugbọn mi o kawe to oye dokita (PhD), oye onipele ikini (BSc) ni mo kawe gba oye rẹ ninu imọ ẹkọ Psychology.

Araale: Awọn ileewe wo ni ẹ lọ?

Seyi: Ile iwe Girama ti ijọ̀ba Odogbolu, Fasiti Olabisi Onabanjo, Fasiti Caleb(mi o pari ti mo fi bẹrẹ iṣẹ), Udegbe North American Univeristy.

Araale: Ta lo fẹran ju lọ ninu gbogbo awọn to kopa ninu ile Ẹlẹgbọn Agba?

Seyi: Mo nifẹẹ gbogbo eniyan ninu ile yẹn tori mo kọ ẹkọ kan latara ẹnikọọkan wọn. Ni bayii mo ti di ẹlomiran tori ẹkọ ti mo kọ lọdọ gbogbo wọn. Ko seeyan kan ni pato, gbogbo wa ni padi.

Araale: Njẹ Seyi n pinu lati dara pọ mọ oṣelu?

Seyi: Mi o sá fun oṣelu ṣugbọn o di tasiko Ọlọrun ba to. Mo fẹ kọkọ ni owo temi na ki wọn ma baa ni mo fẹ wa kowo jẹ nigba ti mo ba kara bọ oṣelu.

Nigba ti wọn mẹnu le ọrọ oriṣiriṣi nkan to tẹyin awọn idije to waye ninu ile, itakurọsọ, ede aiyede, tawọn araale si n jẹwọ ẹni ti wọn fẹ gbaruku ti tabi bi wọn ṣe n ṣi kuro lẹyin ẹnikan bọ sẹyin ẹlomiiran tawọn eeyan wa n jẹ ọrọ Tacha ati Seyi lẹnu, Seyi fesi pe ọrẹ oun ni Tacha. Ko sohun to jọ mọ ede aiyede. "O bu mi gbangba lori ẹrọ amohunmaworan ṣugbọn emi o ka a si, mo ṣi n bá a ṣọrẹ.

Araale: Ẹgbẹ agbabọọlu wo lẹ n ja fun?

Seyi: Manchester United ni o! Super Eagles naa wa nibẹ o, Eyimba Eyimba naa si wa nibẹ ṣugbọn Manu U ni mi o.

BBC: Ṣe ẹ ro pé bi Baba Obafemi Awolowo gan ba wa laye, ṣe wọn a nifẹ si ki ẹ lọ sori eto BBNaija

Seyi: Bẹẹ ni o da mi loju nitori idi pataki to mu mi lọ fun eto naa.

BBC: Igbesẹ wo lẹ n gbé lati ri i pe awọn nkan ti Baba Awoo ṣe silẹ ko parun?

Seyi: Mo ti ṣe agbekalẹ eto kan fun awọn to ni ẹbun pataki lori ẹrọ ayelujara lati jọ pade fun iwulo ara wọn. Ọna ti emi ya niyẹn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKemi Lala: mo ń gbìyànjú láti mú inú òbí mi dùn

Araale: Ṣe Seyi ti fẹyawo atipe ṣe ọmọ alawọdudu ni obinrin naa.

Seyi: A o tii ṣegbeyawo ṣugbọn mo ni 'Baby' kan ti mo nifẹ gan, ẹni bi ọkan mi ni mo si ti wa pa pẹlu ẹ.

Araale: Ṣe ẹ maa n lọ si ilu Ikenne daadaa.

Seyi: Bẹ ni mo ma n lọ si Ikenne daadaa. Koda a jọ n lọ fun ayẹyẹ Ọdun Ereke laipẹ yii.

Araale: Ṣe ẹ n gburo Aunty Tacha? Igba wo ni Seyi ri Tacha gbẹyin?

Seyi: Bẹẹ ni. A ṣi rira ni nkan bii ọgbọn iṣẹju sẹyin. Gbogbo wa jọ wa gẹgẹ bi ọrẹ lasan ni.

Araale: Ki lẹ́ ri kọ gan lori eto BBNaija?

Seyi: Suuru. Keeyan maa fi suuru ṣe nkan.

BBC: Iroyin sọ pe ni igba pipẹ sẹyin, ẹ fẹ gbiyanju lati gba ẹmi ara yin, ki lo fa a?

Seyi: Ọmọde lo n ṣe mi nigba naa. Lati kekere ni ọrọ yii ti ṣẹlẹ o nigba ti mo wa ṣi wa nile iwe girama. Mo mu ago owo goolu to jẹ ti Baba mi, mo wọ ọ lọ sileewe lati fi ṣe fọri fọri fawọn ọrẹ mi. Baba mi si na mi gan to bẹẹ ti mo ro pe nina yẹn ti pọ ju tori naa mo kọ lẹta silẹ mo si gbe nkan jẹ. Nigba to maa fi di owurọ ọjọ keji wọn ti pe le mi lori ṣugbọn a dupẹ mo ṣi n mi. Eyi ni mo fi wa mọ pe wọn fẹran mi.

Lori ọrọ yii ni Seyi fi gba awọn to jẹ pe idojukọ to tun ju ti oun lọ lo n mu wọn fẹ pa ara wọn ara wọn. O ni ko to bẹẹ nitori pe bi mi ba wa, ireti ṣi n bẹ. Eyi loun naa fi de ibi ti oun wa de lonii, bi o ba ti pa ara rẹ, ẹ o ba ma til gb pe ẹnikan wa to n jẹ Seyi.

BBC: Ki lo tun ku ki awọ́n eeyan maa reti lọdọ Seyi lẹyin eto agbelewo Ẹlẹgbọn Agba?

Seyi: Yatọ fun awọn nkan ti mo n ṣe tẹlẹ ki n to l fun eto naa bii arinrinoge, ere agbelewo, maa tun maa ṣe agbekalẹ eto fun awọn eeyan jankanjankan ati pẹlu awọn nkan ti mo n ṣe tẹlẹ.