Uber Boat ṣẹsẹ já ọkọ ojú omi tuntun láti ṣàdínkù súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀

Oko oju omi Image copyright Techcabal facebook
Àkọlé àwòrán Oko oju omi Uber

Ile iṣẹ kan ti a mọ si Uber ti bẹrẹ si ni fi ọkọ oju omi ṣiṣẹ bayi ni ilu Eko.

Ile iṣẹ yii ni wọn ṣẹ ifilọlẹ eto tuntun yii pẹlu ikopa ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri loju omi niluu Eko ni ọjọ Ẹti nigba ti wọn ja awọn ọkọ oju omi tuntun lati fi bẹrẹ eto naa.

Akọkọ rẹ ree ti iru anfaani bayii yoo wa ni ilẹ Naijiria ati ni ilẹ Afirika lapapọ.

Ilu Eko jẹ ibi ti sunkẹrẹ fa kẹrẹ ọkọ ti pọju ni Naijiria ti o si n ṣe akoba fun eto ọrọ aje ati idokowo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èèyàn mi mẹ́ta ló wà nínú ọkọ̀ ojú omi tó dà nù!'

Idi eyi ni ile iṣẹ naa ṣe gbe iru ero bayii kalẹ lati ṣadinku si gbogbo sunkẹrẹ fakẹrẹ igboke gbodo ọkọ.

Ile iṣẹ Uber naa ṣalaye lori ẹrọ ikanni ayelujara wọn pe ọkọ oju omi yii yoo ṣiṣẹ fun ọsẹ meji lati ọjọ kọkanla oṣu yii di ọjọ karundinlọgbọn lati agbegbe Ikorodu si Falọmọ.

Gẹgẹ bi wọn ti ṣe e ni alaye, awọn ero ọkọ yoo maa san Ẹẹdẹgbẹta naira dipo Ẹgbẹrun kan naira ti awọn ọkọ oju omi miiran n gba.

Ẹni ti yoo ba wọ ọkọ oju omi naa ni lati lọ si ori ẹrọ ikanni ayelujara wọn lati beere fun tikẹẹti.

Ile iṣẹ naa wa pa ọwọ pọ pẹlu ile iṣẹ ijọba lpinlẹ Eko ti o wa fun igboke gbodo ọkọ oju omi ati ti ilẹ okeere ti o wa ni Texas .

Gomina Ipinlẹ Eko Babajide Sanwo Olu pẹlu awọn ti wọn jọ kọwọ rin lati wo idaniloju ọkọ naa ni Falọmọ, ilu Eko.