Aisha Buhari: Ẹni tí wọ́n ní ọkọ mi fẹ́ fẹ́ kò mọ̀ pé ìgbéyàwó kò ní wáyé

Aisha Buhari Image copyright @aishambuhari

Iyawo aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Aisha Buhari ti sọ pe, oun ko ni ọrọ lati sọ lori iroyin kan to tan ka laipẹ yii pe, aarẹ Muhammadu Buhari fẹ gbe iyawo miran.

Aisha lo sọ ọrọ yii nigba to n ba akọroyin BBC sọrọ ni kete to gunlẹ si Naijiria lati orilẹ-ede Gẹẹsi.

O ni "Ọkọ mi ni wọn sọ pe o fẹ gbe iyawo, kii ṣe emi, nitori mi o si nile. Nitori naa ọkọ mi nikan lo le ṣalaye bi ọrọ ṣe jẹ."

Aisha tẹsiwaju pe "Ẹni ti wọn ni Buhari yoo gbe niyawo gan ko lero pe igbeyawo naa ko ni waye, nitori o duro titi di igba ti igbeyawo ọhun ko ṣeeṣe, ki obinrin naa to sọrọ lori iroyin naa."

Image copyright @aishambuhari

Nigba to n dahun si bawọn eeyan kan se woye pe o binu fi ile ọkọ rẹ silẹ, to si gba ilẹ okeere lọ, Aisha ni ahesọ lasan ni ọrọ ọhun nitori ko si ohun to jọ bẹẹ.

Iyawo aarẹ ni, irọ ni pe oun fi ibinu fi ile ọkọ oun silẹ, o ni irinajo ti oun lọ wa lati lọ sinmi, ati pe ninu isimi naa ni oun ṣe aisan ranpẹ, ti dokita si gba oun ni imọran lati sinmi diẹ si.

Aisha fikun pe, idi naa lo mu ki ilẹ ta si diẹ, ko to di pe oun pada wa si Naijiria.