Flood: Ìjọba Ondo kéde ìsimi ọ́sẹ̀ mẹ́ta fún àwọn ilé ìwé tó lùgbàdì omíyalé!

Ẹkunn omi Image copyright Getty Images

Ijọba ipinlẹ Ondo ti fun awọn ile iwe kan ni ijọba ibilẹ Ilajẹ ati Ẹsẹ odo ni isimi ọlọsẹ mẹta lọna lati wa ọna abayọ si iṣẹlẹ omiyale to waye ni ipinlẹ naa.

Awọn ile iwe alakọbẹrẹ ati girama ti ọrọ naa kan ni agbara ti ya wọ bayii.

Oluranlọwọ pataki lori ọrọ iroyin fun ijọba ipinlẹ Ondo, Ojo Oyewamide sọ fun BBC pe, bi wọn ṣe ti awọn ile iwe naa jẹ ọna lati wa ojutu si iṣelẹ omiyale naa.

Oyewamide ni ki ṣe gbogbo ile iwe ni ipinlẹ Ondo ni ọrọ naa kan, bikoṣe awọn ile iwe to wa ni ijọba ibilẹ Ilajẹ ati Ẹsẹ odo.

O ṣalaye pe ijọba ti gbe igbimọ kan kalẹ lati boju wo agbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, lọna ati wa ọna abayọ si.

Ijọba ipinlẹ Ondo, labẹ iṣakoso gomina Rotimi Akeredolu ti dari awọn oluṣakoso ile iwe lagbegbe naa, lati ri pe wọn ko ohun elo ikawe ti omi le bajẹ kuro lagbegbe ọhun, titi di igba ti ijọba yoo wa ojutu si ọrọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBangladesh Brothel: Ọ̀pọ̀ àwọn àṣẹ́wó tó wà níbẹ̀ ni wọ́n bí sílé aṣẹ́wó náà