Yollywood: Ẹ wo àwọn ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Mama Rainbow tó pé 77 lóniìí

Idowu Philips, ti apele rẹ n jẹ Mama Rainbow Image copyright MAMARAINBOWOFFICIAL
Àkọlé àwòrán Mama Rainbow pe 77 lonii

Idowu Philips, ti apele rẹ n jẹ Mama Rainbow, tabi Iya Rainbow jẹ mọlumọọka oṣere tiatia Yoruba.

Wọn bi Mama Rainbow ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 1942, ni ilu Ijẹbu Ode, ipinle Ogun, to wa ni iwọ oorun orilẹede Naijiria.

Orukọ "Rainbow" ti wọn n pe Idowu Philips wa latinu Oṣumare to jẹ "Rainbow" ni ede Gẹẹsi.

Orukọ naa si wa lati orukọ ẹgbẹ tiata ọkọ Mama Rainbow tẹlẹ ri.

Ọkọ Mama Rainbow ni Augustine Ayanfemi Phillips, to ṣe iṣe pẹlu aṣaaju-ọna ninu iṣẹ oṣere tiata, Sir Hubert Ogunde, fun ọpọ ọdun.

Iya Rainbow kawe alakọbẹrẹ ati girama ni Ijẹbu Ode, ni ilu kan naa si lo ti lọ ile iwe awọn nọọsi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMama Rainbow: Toyin Adegbola àti Razak Olayiwola ní ìyá rere àti àwòkọ́ṣe gidi ní

Iṣẹ nọọsi ni agba oṣere yii n ṣe fun ogun ọdun o le diẹ, ko to dara pọ mọ ẹgbẹ oṣere tiata.

Ọlọrun fun Iya Rainbow ni ọmọ marun un.

Lẹyin ti Augustine Ayanfemi Phillips to jẹ ọkọ Iya Rainbow jẹ Ọlọrun nipe ni o darapọ mọ iṣẹ oṣere tiata ni kikun.

Image copyright MAMARAINBOWOFFICIAL
Àkọlé àwòrán Mama Rainbow ti kopa ninu ere to le ni ẹẹdẹgbẹta

Ere agbelewo ti Mama Rainbow kọkọ ṣe ni Ẹru, lẹyin naa lo kopa ninu Ajẹ Niya mi, ṣugbọn ere tiata to sọ ọ di mọlumọọka ni Aṣiri Nla.

Mama Rainbow ti kopa ninu ọpọlọpọ ere agbelewo ati ere ori itage.

Lara awọn ere agbelewo ti Iya Rainbow ti kopa ni Back to Africa, lọdun 1997, Lagidigba, to jade lọdun 2000, Kootu Ọlọrun, lọdun 2007, Taiwo Taiwo apa kini ati apa keji to jade lọdun 2008, Oga Bolaji to jade lọdun 2018, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Mama Rainbow ti kopa ninu ere to le ni ẹẹdẹgbẹta, ọpọlọpọ lara awọn ere naa jẹ ni ẹde Yoruba, ṣugbọn o tun ma n kopa ninu ere ti wọn ti n sọ ede Gẹẹsi.