Brexit: Adarí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Boris Johnson ní UK àti EU ti fẹnu Brexit kò

Image copyright @Boris
Àkọlé àwòrán Mo ni idaniloju pe Brexit a ṣẹlẹ - Boris Johnson

UK ati ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu, EU ni wọn ti jọ fẹnuko lori adehun ṣaaju ipade awọn adari ilẹ Yuroopu ni Brussels.

Boris Johnson lo fi ọrọ yii lede loju opo twitter rẹ pe adehun tuntun yii lo dara julọ fun Brexit lasiko yii.

Fun igba akọkọ laarin ọgọrun un ọdun ile igbimọ aṣofin ni London ni a joko ipade lọjọ Abamẹta.

Adehun tuntun ti Johnson n gbero rẹ yii yoo yọ ọna abayọ ti Theresa May la kalẹ fun Brexit ko to lọ.

Laura Kuenssberg to jẹ akọroyin BBC lori oṣelu ni Boris maa beere fun atilẹyin awọn adari ajọ iṣọkan EU nipa pe ki wọn kọ lati fi kun gbendeke asiko ti UK nilo di ipari oṣu yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPainter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!

Alaye ni ṣoki lori erongba Boris fun Brexit tuntun:

Nothern Ireland to wa ni ariwa ni wọn yoo ṣi maa tẹle ofin ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu, EU niwọnba, paapaa awọn ofin to ba niiṣe pẹlu ọja.

Nothern Ireland yoo ṣi wa ni ẹkun aṣa UK ṣugbọn abawọle si UK ni wọn maa fi ṣe agbegbe ti wọn paapaa nibi ọja ẹyọ kan ti ajọ EU.

Pe, adehun maa wa lori otitọ ṣiṣe pẹlu ara wọn ninu ọja kan ṣoṣo ti EU ati pe ki wọn ṣe ohun to yẹ lori owor ori gẹgẹ bi UK ṣe laa kalẹ.

Awọn aṣoju Nothern Ireland lo maa jiroro boya wọn ṣi maa maa tẹle ofin ajọ iṣọkan tabi bẹẹkọ fódun mẹrin.

A ti fẹnu kò lórí ọ̀rọ̀ Brexit- Boris Johnson

UK ati ajọ iṣọkan ilẹ Yureoopu, EU ti fẹnuko lori ọrọ brexit to n ja nilẹ.

Wọn ni bi awọn adari orilẹ-ede mejeeji ṣe n mura lati pade ni Brussels laipẹ.

Image copyright PA Media
Àkọlé àwòrán UK àti EU fẹnukò lórí ọ̀rọ̀ Brexit, sùgbọ́n ẹgbẹ DUP ní kò ní ṣeéṣe.

Adari igbimọ ijọba United Kingdom, Boris Johnson lo fi ọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ pe:

Awọn adari oirlẹ-ede ọhun ni wọn ti n ṣiṣẹ papọ lọna lati fi ẹnu ọrọ Brexit ọhun jona, sugbọn wọn o nilo atilẹyin awọn aṣẹjọba orilẹ-ede mejeeji ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe awọn adari mejeeji naa n fẹ ki ọrọ brexit yii ṣaṣeyọri, ẹgbẹ Democratic Unionist Party, DUP, ni wọn ko ni gba ko ṣeeṣe.

Nini ọrọ ti wọn fi sita ni Northern irish Party ti sọ pe Brexit ko le ṣe anfani kankan fun wọn ni Ariwa Ireland ati pe awọn ṣi duro sori ipinnu wọn.

Loju olori Labour, Jeremy Corbyn nitirẹ, igbesẹ tuntun yii buru ju ti atẹyinwa lọ Theresa May bú sẹ́kún, ó ní òun kò ṣe olóòtú ìjọba UK mọ́.

O ni, koda, ti Theresa May gan an san ju eyi lọ Ta ló máa gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Theresa May?.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'O yé kí ìbáṣepọ̀ Nàìjíríà àti UK dán mọ́rán síi lẹ́yìn àbẹ̀wò May'

Adari igbimọ ijọba United Kingdom, Boris Johnson ati aarẹ European Commision, Jean-Claude Juncker ti rọ awọn aṣofin orillẹ-ede ti ọrọ naa kan, lati ṣe atilẹyin fun Brexit ọhun.

Wọn ti fi lẹta ranṣẹ si Aarẹ igbimọ ilẹ̀ Yuroopu, Donald Tusk pe igbesẹ yii tọna lasiko yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTi o bá dá ara ẹ lójú, ki ẹni tó n ṣe irun kí n gbọ́?