Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!

Aworan nkan to ba n ṣẹlẹ lasiko ti mo fẹ ya aworan ni mo n ya- Samuel.

Odọmọde ayaworan pẹlu gege awọn ọmọde (Pencil), Samuel Ogooluwa Esan ni BBC ba lalejo.

Odọmọde yii maa n ya aworan oriṣiriṣi nipa nkan loriṣiriṣi fun awọn eniyan ni.

Samuel ṣalaye pe awọn nkan to ba n ṣẹlẹ ni ayika oun ati agbegbe oun lo maa n jẹ atọna fun oun lori aworan to yẹ ni yiya.

Ogooluwa ni awọn aworan naa ni oun n ya lati jẹ ki awọn eniyan mọ nkan ti oun ni lọkan ni asiko kọọkan.

Ati pe aworan yiya kii jẹ ki awọn eniyan le gbagbe iṣẹlẹ to ṣẹlẹ nigba kan ri.